Surah 62 · 11 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Jumu'ah in Yoruba
بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
يُسَبِّحُ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ ٱلۡمَلِكِ ٱلۡقُدُّوسِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ
Ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu, Ọba ẹ̀dá, Ẹni-Mímọ́ jùlọ, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
هُوَ ٱلَّذِي بَعَثَ فِي ٱلۡأُمِّيِّـۧنَ رَسُولًا مِّنۡهُمۡ يَتۡلُواْ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِهِۦ وَيُزَكِّيهِمۡ وَيُعَلِّمُهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَإِن كَانُواْ مِن قَبۡلُ لَفِي ضَلَٰلٍ مُّبِينٍ
Òun ni Ẹni tí Ó gbé dìde láààrin àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà (aláìnítírà) Òjíṣẹ́ kan lára wọn. Ó ń ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn. Ó ń fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ó sì ń kọ́ wọn ní Tírà àti ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah), bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé
وَءَاخَرِينَ مِنۡهُمۡ لَمَّا يَلۡحَقُواْ بِهِمۡۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
(Iṣẹ́ jíjẹ́ rẹ̀ tún wà fún) àwọn mìíràn tí wọ́n máa wà nínú àwọn (ọmọlẹ́yìn rẹ̀), àmọ́ tí wọn kò tí ì rìn kàn wọ́n. (Allāhu) Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
ذَٰلِكَ فَضۡلُ ٱللَّهِ يُؤۡتِيهِ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ ذُو ٱلۡفَضۡلِ ٱلۡعَظِيمِ
Ìyẹn ni oore àjùlọ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olóore-àjùlọ ńlá
مَثَلُ ٱلَّذِينَ حُمِّلُواْ ٱلتَّوۡرَىٰةَ ثُمَّ لَمۡ يَحۡمِلُوهَا كَمَثَلِ ٱلۡحِمَارِ يَحۡمِلُ أَسۡفَارَۢاۚ بِئۡسَ مَثَلُ ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِۚ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّٰلِمِينَ
Àpèjúwe ìjọ tí A fún ní Taorāh, lẹ́yìn náà tí wọn kò tẹ̀lé e, ó dà bí àpèjúwe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ru ẹrù àwọn tírà. Aburú ni àpèjúwe àwọn t’ó pe àwọn āyah Allāhu nírọ́. Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí
قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ هَادُوٓاْ إِن زَعَمۡتُمۡ أَنَّكُمۡ أَوۡلِيَآءُ لِلَّهِ مِن دُونِ ٱلنَّاسِ فَتَمَنَّوُاْ ٱلۡمَوۡتَ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ
Sọ pé: "Ẹ̀yin yẹhudi, tí ẹ bá lérò pé dájúdájú ẹ̀yin ni ọ̀rẹ́ Allāhu dípò àwọn ènìyàn (yòókù), ẹ tọrọ ikú nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo
وَلَا يَتَمَنَّوۡنَهُۥٓ أَبَدَۢا بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِٱلظَّٰلِمِينَ
Wọn kò níí tọrọ rẹ̀ láéláé nítorí ohun tí ọwọ́ wọn ti tì ṣíwájú. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí
قُلۡ إِنَّ ٱلۡمَوۡتَ ٱلَّذِي تَفِرُّونَ مِنۡهُ فَإِنَّهُۥ مُلَٰقِيكُمۡۖ ثُمَّ تُرَدُّونَ إِلَىٰ عَٰلِمِ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Sọ pé: "Dájúdájú ikú tí ẹ̀ ń sá fún, dájúdájú ó máa pàdé yín. Lẹ́yìn náà, wọn yóò da yín padà sí ọ̀dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Ó sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا نُودِيَ لِلصَّلَوٰةِ مِن يَوۡمِ ٱلۡجُمُعَةِ فَٱسۡعَوۡاْ إِلَىٰ ذِكۡرِ ٱللَّهِ وَذَرُواْ ٱلۡبَيۡعَۚ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٌ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí wọ́n bá pe ìrun ní ọjọ́ Jum‘ah, ẹ yára lọ síbi ìrántí Allāhu, kí ẹ sì pa kátà-kárà tì. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀
فَإِذَا قُضِيَتِ ٱلصَّلَوٰةُ فَٱنتَشِرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَٱبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِ ٱللَّهِ وَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ كَثِيرًا لَّعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ
Nígbà tí wọ́n bá sì parí ìrun, ẹ túká sí orí ilẹ̀, kí ẹ sì máa wa nínú oore Allāhu. Ẹ rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nítorí kí ẹ lè jèrè
وَإِذَا رَأَوۡاْ تِجَٰرَةً أَوۡ لَهۡوًا ٱنفَضُّوٓاْ إِلَيۡهَا وَتَرَكُوكَ قَآئِمًاۚ قُلۡ مَا عِندَ ٱللَّهِ خَيۡرٌ مِّنَ ٱللَّهۡوِ وَمِنَ ٱلتِّجَٰرَةِۚ وَٱللَّهُ خَيۡرُ ٱلرَّٰزِقِينَ
Nígbà tí wọ́n bá rí ọjà kan tàbí ìranù kan, wọn yóò dà lọ síbẹ̀. Wọn yó sì fi ọ́ sílẹ̀ lórí ìdúró. Sọ pé: "N̄ǹkan tí ó wà ní ọ̀dọ̀ Allāhu l’óore ju ìranù àti ọjà lọ. Allāhu sì l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè
Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.