بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
90:1لَآ أُقۡسِمُ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ
Èmi (Allāhu) búra pẹ̀lú ìlú yìí
90:2وَأَنتَ حِلُّۢ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ
Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀)
90:3وَوَالِدٍ وَمَا وَلَدَ
(Mo tún) búra pẹ̀lú òbí àti ohun t’ó bí
90:4لَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ فِي كَبَدٍ
Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro
90:5أَيَحۡسَبُ أَن لَّن يَقۡدِرَ عَلَيۡهِ أَحَدٌ
Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni
90:6يَقُولُ أَهۡلَكۡتُ مَالًا لُّبَدًا
Ó (sì) ń wí pé: "Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì s.a.w)
90:7أَيَحۡسَبُ أَن لَّمۡ يَرَهُۥٓ أَحَدٌ
Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni
90:8أَلَمۡ نَجۡعَل لَّهُۥ عَيۡنَيۡنِ
Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un
90:9وَلِسَانًا وَشَفَتَيۡنِ
Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)
90:10وَهَدَيۡنَٰهُ ٱلنَّجۡدَيۡنِ
A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n
90:11فَلَا ٱقۡتَحَمَ ٱلۡعَقَبَةَ
Kò sì mú àkàbà ìgbàlà gùn
90:12وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡعَقَبَةُ
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ àkàbà ìgbàlà
90:13فَكُّ رَقَبَةٍ
(Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú
90:14أَوۡ إِطۡعَٰمٌ فِي يَوۡمٍ ذِي مَسۡغَبَةٍ
Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi
90:15يَتِيمًا ذَا مَقۡرَبَةٍ
(Ó lè jẹ́) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí
90:16أَوۡ مِسۡكِينًا ذَا مَتۡرَبَةٍ
tàbí mẹ́kùnnú, ẹni ilẹ̀ẹ́lẹ̀
90:17ثُمَّ كَانَ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلصَّبۡرِ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلۡمَرۡحَمَةِ
Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe
90:18أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ
Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún
90:19وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِنَا هُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَشۡـَٔمَةِ
Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì
90:20عَلَيۡهِمۡ نَارٌ مُّؤۡصَدَةُۢ
A máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá
Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.