Surah 89 · 30 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-Fajr in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

89:1

وَٱلۡفَجۡرِ

Allāhu búra pẹ̀lú àfẹ̀mọ́júmọ́

89:2

وَلَيَالٍ عَشۡرٍ

Ó tún búra pẹ̀lú àwọn òru mẹ́wàá kan

89:3

وَٱلشَّفۡعِ وَٱلۡوَتۡرِ

Ó tún búra pẹ̀lú méjì àti ẹyọ

89:4

وَٱلَّيۡلِ إِذَا يَسۡرِ

Ó tún búra pẹ̀lú òru nígbà tí ó bá lọ (tí ó bá dé)

89:5

هَلۡ فِي ذَٰلِكَ قَسَمٌ لِّذِي حِجۡرٍ

Ǹjẹ́ ìbúra wà nínú ìyẹn fún onílàákàyè

89:6

أَلَمۡ تَرَ كَيۡفَ فَعَلَ رَبُّكَ بِعَادٍ

Ṣé o ò rí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ará ‘Ād

89:7

إِرَمَ ذَاتِ ٱلۡعِمَادِ

(ìyẹn àwọn ìran) ’Irọm, àwọn òmìrán

89:8

ٱلَّتِي لَمۡ يُخۡلَقۡ مِثۡلُهَا فِي ٱلۡبِلَٰدِ

àwọn tí A ò dá irú wọn mọ́ sínú ìlú

89:9

وَثَمُودَ ٱلَّذِينَ جَابُواْ ٱلصَّخۡرَ بِٱلۡوَادِ

Àti àwọn Thamūd tí wọ́n gbẹ́ (ilé ìgbé) sínú àpáta nínú àfonífojì

89:10

وَفِرۡعَوۡنَ ذِي ٱلۡأَوۡتَادِ

àti Fir‘aon eléèkàn (ìyà)

89:11

ٱلَّذِينَ طَغَوۡاْ فِي ٱلۡبِلَٰدِ

(Àwọn wọ̀nyí ni) àwọn t’ó tayọ ẹnu-àlà nínú ìlú

89:12

فَأَكۡثَرُواْ فِيهَا ٱلۡفَسَادَ

Wọ́n sì ṣe ìbàjẹ́ púpọ̀ sínú rẹ̀

89:13

فَصَبَّ عَلَيۡهِمۡ رَبُّكَ سَوۡطَ عَذَابٍ

Olúwa rẹ sì rọ̀jò ìyà lé wọn lórí

89:14

إِنَّ رَبَّكَ لَبِٱلۡمِرۡصَادِ

Dájúdájú Olúwa rẹ wà ní ibùṣọ́ (iṣẹ́ ẹ̀dá)

89:15

فَأَمَّا ٱلۡإِنسَٰنُ إِذَا مَا ٱبۡتَلَىٰهُ رَبُّهُۥ فَأَكۡرَمَهُۥ وَنَعَّمَهُۥ فَيَقُولُ رَبِّيٓ أَكۡرَمَنِ

Nítorí náà, ní ti ènìyàn, nígbà tí Olúwa rẹ̀ bá dán an wò, tí Ó pọ́n ọn lé, tí Ó sì ṣe ìdẹ̀ra fún un, nígbà náà ó máa wí pé: "Olúwa mi ti pọ́n mi lé

89:16

وَأَمَّآ إِذَا مَا ٱبۡتَلَىٰهُ فَقَدَرَ عَلَيۡهِ رِزۡقَهُۥ فَيَقُولُ رَبِّيٓ أَهَٰنَنِ

Ṣùgbọ́n nígbà tí Ó bá dán an wò, tí Ó gán arísìkí rẹ̀ lé e lọ́wọ́, nígbà náà ó máa wí pé: "Olúwa mi ti yẹpẹrẹ mi

89:17

كـَلَّاۖ بَل لَّا تُكۡرِمُونَ ٱلۡيَتِيمَ

Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ẹ̀yin kò ṣàpọ́nlé ọmọ-òrukàn

89:18

وَلَا تَحَٰٓضُّونَ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ

Àti pé ẹ̀yin kò gbẹra yín lóǹgbẹ láti fún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ

89:19

وَتَأۡكُلُونَ ٱلتُّرَاثَ أَكۡلًا لَّمًّا

Ẹ tún ń jẹ ogún ní ìjẹkújẹ

89:20

وَتُحِبُّونَ ٱلۡمَالَ حُبًّا جَمًّا

Àti pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí dúkìá ní ìfẹ́ púpọ̀

89:21

كـَلَّآۖ إِذَا دُكَّتِ ٱلۡأَرۡضُ دَكًّا دَكًّا

Rárá, (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀). Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímì tìtì (t’ó rún wómúwómú, tí kò sí kòtò, tí kò sí gelemọ)

89:22

وَجَآءَ رَبُّكَ وَٱلۡمَلَكُ صَفًّا صَفًّا

(tí) Olúwa rẹ dé pẹ̀lú àwọn mọlāika ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ọ̀wọ̀ọ̀wọ́

89:23

وَجِاْيٓءَ يَوۡمَئِذِۭ بِجَهَنَّمَۚ يَوۡمَئِذٍ يَتَذَكَّرُ ٱلۡإِنسَٰنُ وَأَنَّىٰ لَهُ ٱلذِّكۡرَىٰ

ní ọjọ́ yẹn ni wọ́n máa mú iná Jahanamọ wá. Ní ọjọ́ yẹn, ènìyàn yóò rántí (ọ̀rọ̀ ara rẹ̀). Báwo sì ni ìrántí náà ṣe lè wúlò fún un

89:24

يَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي قَدَّمۡتُ لِحَيَاتِي

Ó máa wí pé: "Yéè, èmi ìbá ti ti (iṣẹ́ rere) síwájú fún ìṣẹ̀mí mi

89:25

فَيَوۡمَئِذٍ لَّا يُعَذِّبُ عَذَابَهُۥٓ أَحَدٌ

Ní ọjọ́ yẹn, ẹnì kan kò lè fi ìyà jẹ (ẹ̀dá) bí irú ìyà (tí) Allāhu (yóò fi jẹ ẹ́)

89:26

وَلَا يُوثِقُ وَثَاقَهُۥٓ أَحَدٌ

Ẹnì kan kò sì lè de (ẹ̀dá) ní ìgbèkùn bí irú ìgbèkùn (tí) Allāhu (yóò fi dè é)

89:27

يَٰٓأَيَّتُهَا ٱلنَّفۡسُ ٱلۡمُطۡمَئِنَّةُ

Ìwọ ẹ̀mí olùfọ̀kànbalẹ̀

89:28

ٱرۡجِعِيٓ إِلَىٰ رَبِّكِ رَاضِيَةً مَّرۡضِيَّةً

padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ní olùyọ́nú, ẹni ìyọ́nú

89:29

فَٱدۡخُلِي فِي عِبَٰدِي

Nítorí náà, wọlé sáààrin àwọn ẹrúsìn Mi

89:30

وَٱدۡخُلِي جَنَّتِي

Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra Mi

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.