Surah 91 · 15 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Ash-Shams in Yoruba
بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
وَٱلۡقَمَرِ إِذَا تَلَىٰهَا
Ó tún búra pẹ̀lú òṣùpá nígbà tí ó bá (yọ) tẹ̀lé (òòrùn)
وَٱلنَّهَارِ إِذَا جَلَّىٰهَا
Ó tún búra pẹ̀lú ọ̀sán nígbà tí ó bá mú ìmọ́lẹ̀ bá òkùnkùn òru
وَنَفۡسٍ وَمَا سَوَّىٰهَا
Ó tún búra pẹ̀lú ẹ̀mí (ènìyàn) àti Ẹni tí Ó ṣe (oríkèé rẹ̀) dọ́gba
فَأَلۡهَمَهَا فُجُورَهَا وَتَقۡوَىٰهَا
Ó sì fi ẹ̀ṣẹ̀ (tí ẹ̀mí lè dá) àti ìbẹ̀rù rẹ̀ mọ̀ ọ́n
قَدۡ أَفۡلَحَ مَن زَكَّىٰهَا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ẹ̀mí ara) rẹ̀ (níbi ẹ̀ṣẹ̀), ó mà ti jèrè
وَقَدۡ خَابَ مَن دَسَّىٰهَا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi (ìwà ẹ̀ṣẹ̀) ba ẹ̀mí (ara) rẹ̀ jẹ́, ó mà ti pàdánù
إِذِ ٱنۢبَعَثَ أَشۡقَىٰهَا
(Rántí) nígbà tí ẹni tí orí rẹ̀ burú jùlọ nínú wọn sáré dìde (láti gún ràkúnmí pa)
فَقَالَ لَهُمۡ رَسُولُ ٱللَّهِ نَاقَةَ ٱللَّهِ وَسُقۡيَٰهَا
Nígbà náà, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ fún wọn pé: "(Ẹ fi) abo ràkúnmí Allāhu àti omi rẹ̀ (sílẹ̀)
فَكَذَّبُوهُ فَعَقَرُوهَا فَدَمۡدَمَ عَلَيۡهِمۡ رَبُّهُم بِذَنۢبِهِمۡ فَسَوَّىٰهَا
Wọ́n pè é nírọ́. Wọ́n sì gún (ràkúnmí) pa. Nítorí náà, Olúwa wọn pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó sì fi ìparun náà kárí wọn
Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.