Surah 94 · 8 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Ash-Sharh in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

94:1

أَلَمۡ نَشۡرَحۡ لَكَ صَدۡرَكَ

Ṣé A ò ṣípayá igbá-àyà rẹ fún ọ bí

94:2

وَوَضَعۡنَا عَنكَ وِزۡرَكَ

A sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò lọ́rùn rẹ

94:3

ٱلَّذِيٓ أَنقَضَ ظَهۡرَكَ

èyí tí ó wọ̀ ọ́ lọ́rùn. àmọ́ tí onítọ̀ún padà gba ’Islām ìbáà jẹ́ pé ó gbà á ní òwúrọ̀

94:4

وَرَفَعۡنَا لَكَ ذِكۡرَكَ

A sì gbé ìrántí orúkọ rẹ ga fún ọ

94:5

فَإِنَّ مَعَ ٱلۡعُسۡرِ يُسۡرًا

Nítorí náà, dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira

94:6

إِنَّ مَعَ ٱلۡعُسۡرِ يُسۡرًا

Dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira sẹ́

94:7

فَإِذَا فَرَغۡتَ فَٱنصَبۡ

Nítorí náà, nígbà tí o bá bùṣe (lórí ọ̀kan), gbìyànjú (òmíràn)

94:8

وَإِلَىٰ رَبِّكَ فَٱرۡغَب

Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni kí o ṣojú kòkòrò oore sí

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.