Surah 85 · 22 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-Buruj in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

85:1

وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلۡبُرُوجِ

(Allāhu) búra pẹ̀lú sánmọ̀ tí àwọn ibùsọ̀ (òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀) wà nínú rẹ̀

85:2

وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡمَوۡعُودِ

Ó tún búra pẹ̀lú ọjọ́ tí wọ́n ṣe ní àdéhùn

85:3

وَشَاهِدٍ وَمَشۡهُودٍ

Ó tún búra pẹ̀lú olùjẹ́rìí àti ohun t’ó jẹ́rìí sí

85:4

قُتِلَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡأُخۡدُودِ

A ṣẹ́bi lé àwọn t’ó gbẹ́ kòtò (iná)

85:5

ٱلنَّارِ ذَاتِ ٱلۡوَقُودِ

(ìyẹn) iná tí wọ́n ń fi igi kò (nínú kòtò)

85:6

إِذۡ هُمۡ عَلَيۡهَا قُعُودٌ

(Rántí) nígbà tí wọ́n jókòó sí ìtòsí rẹ̀

85:7

وَهُمۡ عَلَىٰ مَا يَفۡعَلُونَ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ شُهُودٌ

Wọ́n sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

85:8

وَمَا نَقَمُواْ مِنۡهُمۡ إِلَّآ أَن يُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَمِيدِ

Kò sì sí kiní kan tí wọ́n torí rẹ̀ jẹ wọ́n níyà bí kò ṣe pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, Alágbára, Ọlọ́pẹ́

85:9

ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٍ شَهِيدٌ

Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan

85:10

إِنَّ ٱلَّذِينَ فَتَنُواْ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ ثُمَّ لَمۡ يَتُوبُواْ فَلَهُمۡ عَذَابُ جَهَنَّمَ وَلَهُمۡ عَذَابُ ٱلۡحَرِيقِ

Dájúdájú àwọn t’ó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná t’ó ń jò sì wà fún wọn

85:11

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُمۡ جَنَّٰتٌ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۚ ذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡكَبِيرُ

Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá

85:12

إِنَّ بَطۡشَ رَبِّكَ لَشَدِيدٌ

Dájúdájú ìgbámú ti Olúwa rẹ mà le

85:13

إِنَّهُۥ هُوَ يُبۡدِئُ وَيُعِيدُ

Dájúdájú Òun ni Ó pìlẹ̀ (ẹ̀dá), Ó sì máa dá (ẹ̀dá) padà (fún àjíǹde)

85:14

وَهُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلۡوَدُودُ

Òun ni Aláforíjìn, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá)

85:15

ذُو ٱلۡعَرۡشِ ٱلۡمَجِيدُ

Òun l’Ó ni Ìtẹ́-ọlá, Ẹni-ọ̀wọ̀ jùlọ

85:16

فَعَّالٌ لِّمَا يُرِيدُ

Olùṣe-ohun-t’Ó-bá-fẹ́

85:17

هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ٱلۡجُنُودِ

Ṣebí ìró àwọn ọmọ ogun ti dé ọ̀dọ̀ rẹ

85:18

فِرۡعَوۡنَ وَثَمُودَ

(ọmọ ogun) Fir‘aon àti (ìjọ) Thamūd

85:19

بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فِي تَكۡذِيبٍ

Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ sì ń pe òdodo nírọ́

85:20

وَٱللَّهُ مِن وَرَآئِهِم مُّحِيطُۢ

Allāhu sì yí wọn ká lẹ́yìn wọn

85:21

بَلۡ هُوَ قُرۡءَانٌ مَّجِيدٌ

Àmọ́ sá, ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ni) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé

85:22

فِي لَوۡحٍ مَّحۡفُوظِۭ

tí ó wà nínú wàláà tí À ń ṣọ́

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.