Surah 92 · 21 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-Layl in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

92:1

وَٱلَّيۡلِ إِذَا يَغۡشَىٰ

(Allāhu) búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú

92:2

وَٱلنَّهَارِ إِذَا تَجَلَّىٰ

Ó tún búra pẹ̀lú ọ̀sán nígbà tí (ọ̀sán) bá pọ́n

92:3

وَمَا خَلَقَ ٱلذَّكَرَ وَٱلۡأُنثَىٰٓ

Ó tún búra pẹ̀lú Ẹni tí Ó dá akọ àti abo

92:4

إِنَّ سَعۡيَكُمۡ لَشَتَّىٰ

Dájúdájú iṣẹ́ yín, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni

92:5

فَأَمَّا مَنۡ أَعۡطَىٰ وَٱتَّقَىٰ

Ní ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu)

92:6

وَصَدَّقَ بِٱلۡحُسۡنَىٰ

(tí) ó tún pe ẹ̀san rere ní òdodo

92:7

فَسَنُيَسِّرُهُۥ لِلۡيُسۡرَىٰ

A sì máa ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún un

92:8

وَأَمَّا مَنۢ بَخِلَ وَٱسۡتَغۡنَىٰ

Ní ti ẹni tí ó bá yahun, tí ó sì rí ara rẹ̀ lẹ́ni t’ó rọrọ̀ tayọ ẹ̀san ọ̀run

92:9

وَكَذَّبَ بِٱلۡحُسۡنَىٰ

(tí) ó tún pe ẹ̀san rere ní irọ́

92:10

فَسَنُيَسِّرُهُۥ لِلۡعُسۡرَىٰ

A sì máa ṣe iṣẹ́ aburú ní ìrọ̀rùn fún un

92:11

وَمَا يُغۡنِي عَنۡهُ مَالُهُۥٓ إِذَا تَرَدَّىٰٓ

Dúkìá rẹ̀ kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ nígbà tí ó bá já bọ́ (sínú Iná)

92:12

إِنَّ عَلَيۡنَا لَلۡهُدَىٰ

Dájúdájú tiWa ni (láti ṣàlàyé) ìmọ̀nà

92:13

وَإِنَّ لَنَا لَلۡأٓخِرَةَ وَٱلۡأُولَىٰ

Àti pé dájúdájú tiWa ni ọ̀run àti ayé

92:14

فَأَنذَرۡتُكُمۡ نَارًا تَلَظَّىٰ

Nítorí náà, Mo ti fi Iná eléjò fòfò kìlọ̀ fun yín

92:15

لَا يَصۡلَىٰهَآ إِلَّا ٱلۡأَشۡقَى

Kò sí ẹni tí ó máa wọ inú rẹ̀ àfi olórí burúkú

92:16

ٱلَّذِي كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ

ẹni tí ó pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i

92:17

وَسَيُجَنَّبُهَا ٱلۡأَتۡقَى

Wọ́n sì máa gbé (Iná) jìnnà sí olùbẹ̀rù (Allāhu)

92:18

ٱلَّذِي يُؤۡتِي مَالَهُۥ يَتَزَكَّىٰ

ẹni t’ó ń fi dúkìá rẹ̀ tọrẹ, tí ó ń ṣàfọ̀mọ́ (rẹ̀)

92:19

وَمَا لِأَحَدٍ عِندَهُۥ مِن نِّعۡمَةٍ تُجۡزَىٰٓ

Kò sì sí oore ìdẹ̀ra kan tí (ó ní lọ́kàn) láti gbà ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni

92:20

إِلَّا ٱبۡتِغَآءَ وَجۡهِ رَبِّهِ ٱلۡأَعۡلَىٰ

bí kò ṣe pé láti fi wá ojú rere Olúwa rẹ̀, Ẹni Gíga jùlọ

92:21

وَلَسَوۡفَ يَرۡضَىٰ

Láìpẹ́ ó sì máa yọ́nú (sí ẹ̀san rẹ̀)

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.