Surah 82 · 19 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-Infitar in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

82:1

إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنفَطَرَتۡ

Nígbà tí sánmọ̀ bá fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ

82:2

وَإِذَا ٱلۡكَوَاكِبُ ٱنتَثَرَتۡ

àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri

82:3

وَإِذَا ٱلۡبِحَارُ فُجِّرَتۡ

àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn

82:4

وَإِذَا ٱلۡقُبُورُ بُعۡثِرَتۡ

àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè

82:5

عَلِمَتۡ نَفۡسٌ مَّا قَدَّمَتۡ وَأَخَّرَتۡ

(nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀)

82:6

يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡإِنسَٰنُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ ٱلۡكَرِيمِ

Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé

82:7

ٱلَّذِي خَلَقَكَ فَسَوَّىٰكَ فَعَدَلَكَ

Ẹni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn

82:8

فِيٓ أَيِّ صُورَةٍ مَّا شَآءَ رَكَّبَكَ

Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́

82:9

كـَلَّا بَلۡ تُكَذِّبُونَ بِٱلدِّينِ

Ní ti òdodo, ńṣe l’ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́

82:10

وَإِنَّ عَلَيۡكُمۡ لَحَٰفِظِينَ

Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín

82:11

كِرَامًا كَٰتِبِينَ

(Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá

82:12

يَعۡلَمُونَ مَا تَفۡعَلُونَ

Wọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

82:13

إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٍ

Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn

82:14

وَإِنَّ ٱلۡفُجَّارَ لَفِي جَحِيمٍ

Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm

82:15

يَصۡلَوۡنَهَا يَوۡمَ ٱلدِّينِ

Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san

82:16

وَمَا هُمۡ عَنۡهَا بِغَآئِبِينَ

Wọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀

82:17

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san

82:18

ثُمَّ مَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ

Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san

82:19

يَوۡمَ لَا تَمۡلِكُ نَفۡسٌ لِّنَفۡسٍ شَيۡـًٔاۖ وَٱلۡأَمۡرُ يَوۡمَئِذٍ لِّلَّهِ

(Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.