Surah 81 · 29 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah At-Takwir in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

81:1

إِذَا ٱلشَّمۡسُ كُوِّرَتۡ

Nígbà tí Wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù

81:2

وَإِذَا ٱلنُّجُومُ ٱنكَدَرَتۡ

àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri

81:3

وَإِذَا ٱلۡجِبَالُ سُيِّرَتۡ

àti nígbà tí Wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù)

81:4

وَإِذَا ٱلۡعِشَارُ عُطِّلَتۡ

àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì

81:5

وَإِذَا ٱلۡوُحُوشُ حُشِرَتۡ

àti nígbà tí Wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ

81:6

وَإِذَا ٱلۡبِحَارُ سُجِّرَتۡ

àti nígbà tí Wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná

81:7

وَإِذَا ٱلنُّفُوسُ زُوِّجَتۡ

àti nígbà tí Wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)

81:8

وَإِذَا ٱلۡمَوۡءُۥدَةُ سُئِلَتۡ

àti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé

81:9

بِأَيِّ ذَنۢبٍ قُتِلَتۡ

ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n pa òun fún

81:10

وَإِذَا ٱلصُّحُفُ نُشِرَتۡ

àti nígbà tí Wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀

81:11

وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ كُشِطَتۡ

àti nígbà tí Wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè

81:12

وَإِذَا ٱلۡجَحِيمُ سُعِّرَتۡ

àti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò

81:13

وَإِذَا ٱلۡجَنَّةُ أُزۡلِفَتۡ

àti nígbà tí Wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo)

81:14

عَلِمَتۡ نَفۡسٌ مَّآ أَحۡضَرَتۡ

(nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi)

81:15

فَلَآ أُقۡسِمُ بِٱلۡخُنَّسِ

Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú àwọn ìràwọ̀ t’ó ń yọ ní alẹ́, t’ó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán

81:16

ٱلۡجَوَارِ ٱلۡكُنَّسِ

(ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ t’ó ń rìn lọ rìn bọ̀, t’ó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn

81:17

وَٱلَّيۡلِ إِذَا عَسۡعَسَ

Mo tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá lọ

81:18

وَٱلصُّبۡحِ إِذَا تَنَفَّسَ

Mo tún búra pẹ̀lú òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀

81:19

إِنَّهُۥ لَقَوۡلُ رَسُولٍ كَرِيمٍ

Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé

81:20

ذِي قُوَّةٍ عِندَ ذِي ٱلۡعَرۡشِ مَكِينٍ

alágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá

81:21

مُّطَاعٍ ثَمَّ أَمِينٍ

ẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán

81:22

وَمَا صَاحِبُكُم بِمَجۡنُونٍ

Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad s.a.w.) kì í ṣe wèrè

81:23

وَلَقَدۡ رَءَاهُ بِٱلۡأُفُقِ ٱلۡمُبِينِ

Ó kúkú rí i nínú òfurufú kedere

81:24

وَمَا هُوَ عَلَى ٱلۡغَيۡبِ بِضَنِينٍ

Àti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i)

81:25

وَمَا هُوَ بِقَوۡلِ شَيۡطَٰنٍ رَّجِيمٍ

Al-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀

81:26

فَأَيۡنَ تَذۡهَبُونَ

Nítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ

81:27

إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرٌ لِّلۡعَٰلَمِينَ

Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá

81:28

لِمَن شَآءَ مِنكُمۡ أَن يَسۡتَقِيمَ

(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé

81:29

وَمَا تَشَآءُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.