Surah 96 · 19 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-'Alaq in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

96:1

ٱقۡرَأۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلَّذِي خَلَقَ

Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá

96:2

خَلَقَ ٱلۡإِنسَٰنَ مِنۡ عَلَقٍ

Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì

96:3

ٱقۡرَأۡ وَرَبُّكَ ٱلۡأَكۡرَمُ

Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ

96:4

ٱلَّذِي عَلَّمَ بِٱلۡقَلَمِ

Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn

96:5

عَلَّمَ ٱلۡإِنسَٰنَ مَا لَمۡ يَعۡلَمۡ

Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n

96:6

كـَلَّآ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَيَطۡغَىٰٓ

Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-àlà

96:7

أَن رَّءَاهُ ٱسۡتَغۡنَىٰٓ

nítorí pé ó ríra rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀

96:8

إِنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلرُّجۡعَىٰٓ

Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá

96:9

أَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي يَنۡهَىٰ

Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ń kọ̀

96:10

عَبۡدًا إِذَا صَلَّىٰٓ

fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun

96:11

أَرَءَيۡتَ إِن كَانَ عَلَى ٱلۡهُدَىٰٓ

Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)

96:12

أَوۡ أَمَرَ بِٱلتَّقۡوَىٰٓ

tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)

96:13

أَرَءَيۡتَ إِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰٓ

Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i

96:14

أَلَمۡ يَعۡلَم بِأَنَّ ٱللَّهَ يَرَىٰ

Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni)

96:15

كـَلَّا لَئِن لَّمۡ يَنتَهِ لَنَسۡفَعَۢا بِٱلنَّاصِيَةِ

Bẹ́ẹ̀ ni (Allāhu ń rí i.) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí i lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná)

96:16

نَاصِيَةٍ كَٰذِبَةٍ خَاطِئَةٍ

àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀

96:17

فَلۡيَدۡعُ نَادِيَهُۥ

Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀

96:18

سَنَدۡعُ ٱلزَّبَانِيَةَ

Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná

96:19

كـَلَّا لَا تُطِعۡهُ وَٱسۡجُدۡۤ وَٱقۡتَرِب

Rárá o, má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o súnmọ́ (Allāhu)

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.