Surah 80 · 42 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah 'Abasa in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

80:1

عَبَسَ وَتَوَلَّىٰٓ

(Ànábì s.a.w.) fajú ro, ó sì pẹ̀yìn dà

80:2

أَن جَآءَهُ ٱلۡأَعۡمَىٰ

nítorí pé afọ́jú wá bá a

80:3

وَمَا يُدۡرِيكَ لَعَلَّهُۥ يَزَّكَّىٰٓ

Kí sì l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́)

80:4

أَوۡ يَذَّكَّرُ فَتَنفَعَهُ ٱلذِّكۡرَىٰٓ

tàbí kí ó gbọ́ ìrántí, kí ìrántí náà sì ṣe é ní àǹfààní

80:5

أَمَّا مَنِ ٱسۡتَغۡنَىٰ

Ní ti ẹni tí ó ka ara rẹ̀ kún ọlọ́rọ̀

80:6

فَأَنتَ لَهُۥ تَصَدَّىٰ

òun ni ìwọ tẹ́tí sí

80:7

وَمَا عَلَيۡكَ أَلَّا يَزَّكَّىٰ

Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ bí kò bá ṣe àfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́)

80:8

وَأَمَّا مَن جَآءَكَ يَسۡعَىٰ

Ní ti ẹni tí ó sì wá bá ọ, t’ó ń yára gágá (sí ìrántí, ìyẹn afọ́jú)

80:9

وَهُوَ يَخۡشَىٰ

tí ó sì ń páyà (Allāhu)

80:10

فَأَنتَ عَنۡهُ تَلَهَّىٰ

ìwọ kò sì kọbi ara sí i

80:11

كـَلَّآ إِنَّهَا تَذۡكِرَةٌ

Rárá (kò tọ́ bẹ́ẹ̀). Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí

80:12

فَمَن شَآءَ ذَكَرَهُۥ

Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó rántí rẹ̀

80:13

فِي صُحُفٍ مُّكَرَّمَةٍ

(Al-Ƙur’ān) wà nínú àwọn tàkádà alápọ̀n-ọ́nlé

80:14

مَّرۡفُوعَةٍ مُّطَهَّرَةِۭ

A gbé e ga, A sì ṣe é ní mímọ́

80:15

بِأَيۡدِي سَفَرَةٍ

ní ọwọ́ àwọn òǹkọtíà (ìyẹn, àwọn mọlāika)

80:16

كِرَامِۭ بَرَرَةٍ

àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, àwọn ẹni rere

80:17

قُتِلَ ٱلۡإِنسَٰنُ مَآ أَكۡفَرَهُۥ

Wọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ

80:18

مِنۡ أَيِّ شَيۡءٍ خَلَقَهُۥ

Kí sì ni Allāhu fi ṣẹ̀dá rẹ̀

80:19

مِن نُّطۡفَةٍ خَلَقَهُۥ فَقَدَّرَهُۥ

Nínú àtọ̀ l’Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀

80:20

ثُمَّ ٱلسَّبِيلَ يَسَّرَهُۥ

Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un

80:21

ثُمَّ أَمَاتَهُۥ فَأَقۡبَرَهُۥ

Lẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè

80:22

ثُمَّ إِذَا شَآءَ أَنشَرَهُۥ

Lẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde

80:23

كـَلَّا لَمَّا يَقۡضِ مَآ أَمَرَهُۥ

Ẹ gbọ́, ènìyàn kò tí ì ṣe n̄ǹkan tí Allāhu pa láṣẹ fún un

80:24

فَلۡيَنظُرِ ٱلۡإِنسَٰنُ إِلَىٰ طَعَامِهِۦٓ

Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí oúnjẹ rẹ̀

80:25

أَنَّا صَبَبۡنَا ٱلۡمَآءَ صَبًّا

Dájúdájú Àwa ń rọ òjò ní púpọ̀

80:26

ثُمَّ شَقَقۡنَا ٱلۡأَرۡضَ شَقًّا

Lẹ́yìn náà, A mú ilẹ̀ sán kànkàn

80:27

فَأَنۢبَتۡنَا فِيهَا حَبًّا

A sì mú kóró èso hù jáde láti inú rẹ̀

80:28

وَعِنَبًا وَقَضۡبًا

àti èso àjàrà àti kànnáfùrù

80:29

وَزَيۡتُونًا وَنَخۡلًا

àti igi òróró Zaetūn àti dàbínù

80:30

وَحَدَآئِقَ غُلۡبًا

àti àwọn ọgbà t’ó kún fún igi

80:31

وَفَٰكِهَةً وَأَبًّا

àti àwọn èso (mìíràn) pẹ̀lú ewé tí ẹranko ń jẹ, (A mú wọn hù jáde)

80:32

مَّتَٰعًا لَّكُمۡ وَلِأَنۡعَٰمِكُمۡ

(Wọ́n jẹ́ n̄ǹkan) ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn ẹran-ọ̀sìn yín

80:33

فَإِذَا جَآءَتِ ٱلصَّآخَّةُ

Nígbà tí fífọn sínú ìwo nígbà kejì bá ṣẹlẹ̀

80:34

يَوۡمَ يَفِرُّ ٱلۡمَرۡءُ مِنۡ أَخِيهِ

ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún arákùnrin rẹ̀

80:35

وَأُمِّهِۦ وَأَبِيهِ

àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú bàbá rẹ̀

80:36

وَصَٰحِبَتِهِۦ وَبَنِيهِ

àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀

80:37

لِكُلِّ ٱمۡرِيٍٕ مِّنۡهُمۡ يَوۡمَئِذٍ شَأۡنٌ يُغۡنِيهِ

Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ọjọ́ yẹn l’ó ti ní ọ̀ràn t’ó máa tó o ó rán

80:38

وُجُوهٌ يَوۡمَئِذٍ مُّسۡفِرَةٌ

Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn yóò mọ́lẹ̀

80:39

ضَاحِكَةٌ مُّسۡتَبۡشِرَةٌ

Wọn yó máa rẹ́rìn-ín, wọn yó sì máa dunnú

80:40

وَوُجُوهٌ يَوۡمَئِذٍ عَلَيۡهَا غَبَرَةٌ

Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn ni eruku yó sì bò mọ́lẹ̀

80:41

تَرۡهَقُهَا قَتَرَةٌ

Òkùnkùn yó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀

80:42

أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡكَفَرَةُ ٱلۡفَجَرَةُ

Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.