بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
88:1هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ٱلۡغَٰشِيَةِ
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ohun t’ó máa bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ ti dé ọ̀dọ̀ rẹ
88:2وُجُوهٌ يَوۡمَئِذٍ خَٰشِعَةٌ
Àwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn
88:3عَامِلَةٌ نَّاصِبَةٌ
Oníṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni wọ́n nílé ayé)
88:4تَصۡلَىٰ نَارًا حَامِيَةً
Wọ́n máa wọ inú Iná t’ó gbóná janjan (ní ọ̀run)
88:5تُسۡقَىٰ مِنۡ عَيۡنٍ ءَانِيَةٍ
Wọ́n sì máa fún (wọn) ní omi gbígbóná mu
88:6لَّيۡسَ لَهُمۡ طَعَامٌ إِلَّا مِن ضَرِيعٍ
Kò sí oúnjẹ kan fún wọn àyàfi igi ẹlẹ́gùn-ún gbígbẹ
88:7لَّا يُسۡمِنُ وَلَا يُغۡنِي مِن جُوعٍ
Kò níí mú wọn sanra. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ebi
88:8وُجُوهٌ يَوۡمَئِذٍ نَّاعِمَةٌ
Àwọn ojú kan yó sì kún fún ìgbádùn ní ọjọ́ yẹn
88:9لِّسَعۡيِهَا رَاضِيَةٌ
nítorí pé (ó) yọ́nú sí (ẹ̀san) iṣẹ́ rẹ̀
88:10فِي جَنَّةٍ عَالِيَةٍ
(Ó máa) wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga
88:11لَّا تَسۡمَعُ فِيهَا لَٰغِيَةً
Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀
88:12فِيهَا عَيۡنٌ جَارِيَةٌ
Omi ìṣẹ́lẹ̀rú t’ó ń ṣàn wà nínú rẹ̀
88:13فِيهَا سُرُرٌ مَّرۡفُوعَةٌ
Àwọn ibùsùn tí wọ́n gbé sókè wà nínú rẹ̀
88:14وَأَكۡوَابٌ مَّوۡضُوعَةٌ
àti àwọn ife ìmumi tí wọ́n gbé kalẹ̀ (sí àrọ́wọ́tó wọn)
88:15وَنَمَارِقُ مَصۡفُوفَةٌ
àti àwọn ìrọ̀rí tí wọ́n tò sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn
88:16وَزَرَابِيُّ مَبۡثُوثَةٌ
àti àwọn ìtẹ́ àtẹ́ẹ̀ká
88:17أَفَلَا يَنظُرُونَ إِلَى ٱلۡإِبِلِ كَيۡفَ خُلِقَتۡ
Nítorí náà, ṣé wọn kò wo ràkúnmí, bí A ti ṣẹ̀dá rẹ̀ ni
88:18وَإِلَى ٱلسَّمَآءِ كَيۡفَ رُفِعَتۡ
àti sánmọ̀, bí A ti ṣe gbé e sókè
88:19وَإِلَى ٱلۡجِبَالِ كَيۡفَ نُصِبَتۡ
àti àpáta, bí A ti ṣe gbé e nàró (sínú ilẹ̀)
88:20وَإِلَى ٱلۡأَرۡضِ كَيۡفَ سُطِحَتۡ
àti ilẹ̀, bí A ti ṣe tẹ́ ẹ sílẹ̀ ní gban̄sasa
88:21فَذَكِّرۡ إِنَّمَآ أَنتَ مُذَكِّرٌ
Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kúkú ni olùṣèràntí
88:22لَّسۡتَ عَلَيۡهِم بِمُصَيۡطِرٍ
Ìwọ kì í ṣe ajẹni-nípá lórí wọn
88:23إِلَّا مَن تَوَلَّىٰ وَكَفَرَ
àfi ẹni tí ó bá pẹ̀yìndà (sí òdodo), tí ó sì ṣàì gbàgbọ́
88:24فَيُعَذِّبُهُ ٱللَّهُ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَكۡبَرَ
Allāhu sì máa jẹ ẹ́ níyà t’ó tóbi jùlọ
88:25إِنَّ إِلَيۡنَآ إِيَابَهُمۡ
Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà
88:26ثُمَّ إِنَّ عَلَيۡنَا حِسَابَهُم
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn
Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.