Surah 75 · 40 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-Qiyamah in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

75:1

لَآ أُقۡسِمُ بِيَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ

Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú Ọjọ́ Àjíǹde

75:2

وَلَآ أُقۡسِمُ بِٱلنَّفۡسِ ٱللَّوَّامَةِ

Mo tún ń búra pẹ̀lú ẹ̀mí t’ó máa dára rẹ̀ lẹ́bi

75:3

أَيَحۡسَبُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَلَّن نَّجۡمَعَ عِظَامَهُۥ

Ṣé ènìyàn lérò pé A ò níí kó àwọn eegun rẹ̀ jọ ni

75:4

بَلَىٰ قَٰدِرِينَ عَلَىٰٓ أَن نُّسَوِّيَ بَنَانَهُۥ

Rárá o. A lágbára láti to eegun ọmọníka rẹ̀ dọ́gba

75:5

بَلۡ يُرِيدُ ٱلۡإِنسَٰنُ لِيَفۡجُرَ أَمَامَهُۥ

Ṣùgbọ́n ènìyàn gbèrò láti pe (Ọjọ́ Àjíǹde) t’ó ń bẹ níwájú rẹ̀ nírọ́

75:6

يَسۡـَٔلُ أَيَّانَ يَوۡمُ ٱلۡقِيَٰمَةِ

Ó ń bèèrè pé: "Ìgbà wo ni Ọjọ́ Àjíǹde

75:7

فَإِذَا بَرِقَ ٱلۡبَصَرُ

Nígbà tí ojú bá kọ mọ̀nà

75:8

وَخَسَفَ ٱلۡقَمَرُ

àti (nígbà) tí òṣùpá bá wọ̀ọ̀kùn

75:9

وَجُمِعَ ٱلشَّمۡسُ وَٱلۡقَمَرُ

àti (nígbà) tí A bá pa òòrùn àti òṣùpá pọ̀ mọ́ra wọn

75:10

يَقُولُ ٱلۡإِنسَٰنُ يَوۡمَئِذٍ أَيۡنَ ٱلۡمَفَرُّ

ènìyàn yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé: "Níbo ni ibùsásí wà

75:11

كـَلَّا لَا وَزَرَ

Rárá, kò sí ibùsásí

75:12

إِلَىٰ رَبِّكَ يَوۡمَئِذٍ ٱلۡمُسۡتَقَرُّ

Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni ibùdúró ní ọjọ́ yẹn

75:13

يُنَبَّؤُاْ ٱلۡإِنسَٰنُ يَوۡمَئِذِۭ بِمَا قَدَّمَ وَأَخَّرَ

Wọ́n máa fún ènìyàn ní ìró ní ọjọ́ yẹn nípa ohun t’ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun t’ó fi kẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀)

75:14

بَلِ ٱلۡإِنسَٰنُ عَلَىٰ نَفۡسِهِۦ بَصِيرَةٌ

Ṣebí ènìyàn dá ara rẹ̀ mọ̀

75:15

وَلَوۡ أَلۡقَىٰ مَعَاذِيرَهُۥ

ìbáà mú àwọn àwáwí rẹ̀ wá

75:16

لَا تُحَرِّكۡ بِهِۦ لِسَانَكَ لِتَعۡجَلَ بِهِۦٓ

Má ṣe gbé ahọ́n rẹ sí ìmísí láti kánjú ké e

75:17

إِنَّ عَلَيۡنَا جَمۡعَهُۥ وَقُرۡءَانَهُۥ

Dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìkójọ rẹ̀ (sínú ọkàn rẹ) àti kíké rẹ̀

75:18

فَإِذَا قَرَأۡنَٰهُ فَٱتَّبِعۡ قُرۡءَانَهُۥ

Nígbà tí A bá ń ké e (fún ọ), kí o sì máa tẹ̀lé kíké rẹ̀

75:19

ثُمَّ إِنَّ عَلَيۡنَا بَيَانَهُۥ

Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ

75:20

كـَلَّا بَلۡ تُحِبُّونَ ٱلۡعَاجِلَةَ

Ẹ gbọ́! Ńṣe l’ẹ nífẹ̀ẹ́ ayé

75:21

وَتَذَرُونَ ٱلۡأٓخِرَةَ

Ẹ sì ń pa ọ̀run tì

75:22

وُجُوهٌ يَوۡمَئِذٍ نَّاضِرَةٌ

Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn yóò tutù (fún ìdùnnú)

75:23

إِلَىٰ رَبِّهَا نَاظِرَةٌ

Olúwa wọn ni wọn yóò máa wò

75:24

وَوُجُوهٌ يَوۡمَئِذِۭ بَاسِرَةٌ

Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn sì máa bàjẹ́

75:25

تَظُنُّ أَن يُفۡعَلَ بِهَا فَاقِرَةٌ

(Ojú náà) yóò mọ̀ dájú pé Wọ́n máa fi aburú kan òhun

75:26

كـَلَّآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلتَّرَاقِيَ

Ẹ gbọ́! Nígbà tí ẹ̀mí bá dé gògòńgò

75:27

وَقِيلَ مَنۡۜ رَاقٍ

A sì máa sọ pé: "Ǹjẹ́ ọlọ́fọ̀ pípè kan wà bí (tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú)

75:28

وَظَنَّ أَنَّهُ ٱلۡفِرَاقُ

Ó sì máa dá a lójú pé dájúdájú ìpínyà ayé ti dé

75:29

وَٱلۡتَفَّتِ ٱلسَّاقُ بِٱلسَّاقِ

Ojúgun yó sì lọ́mọ́ ojúgun

75:30

إِلَىٰ رَبِّكَ يَوۡمَئِذٍ ٱلۡمَسَاقُ

Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni wíwa ẹ̀dá lọ ní ọjọ́ yẹn

75:31

فَلَا صَدَّقَ وَلَا صَلَّىٰ

Kò kúkú gba òdodo gbọ́, kò sì kírun

75:32

وَلَٰكِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ

Ṣùgbọ́n ó pe òdodo nírọ́. Ó sì kẹ̀yìn sí i

75:33

ثُمَّ ذَهَبَ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ يَتَمَطَّىٰٓ

Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń ṣe fáàrí

75:34

أَوۡلَىٰ لَكَ فَأَوۡلَىٰ

Ègbé ni fún ọ, ègbé ni sẹ́

75:35

ثُمَّ أَوۡلَىٰ لَكَ فَأَوۡلَىٰٓ

Lẹ́yìn náà, ègbé ni fún ọ, ègbé sì sẹ́

75:36

أَيَحۡسَبُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَن يُتۡرَكَ سُدًى

Ṣé ènìyàn lérò pé A máa fi òun sílẹ̀ lásán ni

75:37

أَلَمۡ يَكُ نُطۡفَةً مِّن مَّنِيٍّ يُمۡنَىٰ

Ṣé kò ti jẹ́ àtọ̀ mọnī tí wọ́n dà jáde sínú àpòlùkẹ́ ni

75:38

ثُمَّ كَانَ عَلَقَةً فَخَلَقَ فَسَوَّىٰ

Lẹ́yìn náà, ó di ẹ̀jẹ̀ dídì. (Allāhu) sì ṣẹ̀dá (rẹ̀). Ó sì ṣe é t’ó dọ́gba jálẹ̀ léèyàn

75:39

فَجَعَلَ مِنۡهُ ٱلزَّوۡجَيۡنِ ٱلذَّكَرَ وَٱلۡأُنثَىٰٓ

(Allāhu) sì ṣe ìran méjì jáde láti inú rẹ̀, akọ àti abo

75:40

أَلَيۡسَ ذَٰلِكَ بِقَٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يُحۡـِۧيَ ٱلۡمَوۡتَىٰ

Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣe ìyẹn kò níí ní agbára láti jí àwọn òkú dìde bí

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.