Surah 74 · 56 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-Muddaththir in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

74:1

يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡمُدَّثِّرُ

Ìwọ olùdaṣọbora

74:2

قُمۡ فَأَنذِرۡ

Dìde kí o ṣèkìlọ̀

74:3

وَرَبَّكَ فَكَبِّرۡ

Olúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún

74:4

وَثِيَابَكَ فَطَهِّرۡ

Aṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́

74:5

وَٱلرُّجۡزَ فَٱهۡجُرۡ

Òrìṣà ni kí o jìnnà sí

74:6

وَلَا تَمۡنُن تَسۡتَكۡثِرُ

Má ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà

74:7

وَلِرَبِّكَ فَٱصۡبِرۡ

Olúwa rẹ ni kí o ṣe sùúrù fún

74:8

فَإِذَا نُقِرَ فِي ٱلنَّاقُورِ

Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde

74:9

فَذَٰلِكَ يَوۡمَئِذٍ يَوۡمٌ عَسِيرٌ

ìyẹn, ní ọjọ́ yẹn, ni ọjọ́ ìnira

74:10

عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ غَيۡرُ يَسِيرٍ

tí kò níí rọrùn fún àwọn aláìgbàgbọ́

74:11

ذَرۡنِي وَمَنۡ خَلَقۡتُ وَحِيدًا

Fi Mí dá ẹni tí Mo dá ní òun nìkan

74:12

وَجَعَلۡتُ لَهُۥ مَالًا مَّمۡدُودًا

Mo sì fún un ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá

74:13

وَبَنِينَ شُهُودًا

àti àwọn ọmọkúnrin t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀

74:14

وَمَهَّدتُّ لَهُۥ تَمۡهِيدًا

Mo sì ṣe ayé nírọ̀rùn fún un gan-an

74:15

ثُمَّ يَطۡمَعُ أَنۡ أَزِيدَ

Lẹ́yìn náà, ó tún ń jẹ̀rankàn pé kí N̄g ṣe àlékún

74:16

كـَلَّآۖ إِنَّهُۥ كَانَ لِأٓيَٰتِنَا عَنِيدًا

Rárá o! Dájúdájú ó jẹ́ alátakò sí àwọn āyah Wa

74:17

سَأُرۡهِقُهُۥ صَعُودًا

Èmi yóò la ìyà pọ́nkèpọ́nkè bọ̀ ọ́ lọ́rùn (nínú Iná)

74:18

إِنَّهُۥ فَكَّرَ وَقَدَّرَ

Dájúdájú ó ronú (lódì nípa al-Ƙur’ān). Ó sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀mí rẹ̀)

74:19

فَقُتِلَ كَيۡفَ قَدَّرَ

Wọ́n sì ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu

74:20

ثُمَّ قُتِلَ كَيۡفَ قَدَّرَ

Lẹ́yìn náà, Wọ́n tún ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu

74:21

ثُمَّ نَظَرَ

Lẹ́yìn náà, ó wò sùn

74:22

ثُمَّ عَبَسَ وَبَسَرَ

Lẹ́yìn náà, ó fajú ro, ó sì dijú mágbárí

74:23

ثُمَّ أَدۡبَرَ وَٱسۡتَكۡبَرَ

Lẹ́yìn náà, ó pẹ̀yìn dà, ó sì ṣègbéraga

74:24

فَقَالَ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٌ يُؤۡثَرُ

Ó sì wí pé: "Kí ni èyí bí kò ṣe idán àtọwọ́dọ́wọ́

74:25

إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا قَوۡلُ ٱلۡبَشَرِ

Kí ni èyí bí kò ṣe ọ̀rọ̀ abara

74:26

سَأُصۡلِيهِ سَقَرَ

Èmi yóò fi sínú iná Saƙọr

74:27

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا سَقَرُ

Kí l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ iná Saƙọr

74:28

لَا تُبۡقِي وَلَا تَذَرُ

(Saƙọr) kò níí ṣẹ́ ẹ kù, kò sì níí pa á tì

74:29

لَوَّاحَةٌ لِّلۡبَشَرِ

Ó máa jó awọ ara di dúdú

74:30

عَلَيۡهَا تِسۡعَةَ عَشَرَ

(Àwọn mọlāika) mọ́kàndínlógún ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀

74:31

وَمَا جَعَلۡنَآ أَصۡحَٰبَ ٱلنَّارِ إِلَّا مَلَٰٓئِكَةًۖ وَمَا جَعَلۡنَا عِدَّتَهُمۡ إِلَّا فِتۡنَةً لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ لِيَسۡتَيۡقِنَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ وَيَزۡدَادَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِيمَٰنًا وَلَا يَرۡتَابَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡمُؤۡمِنُونَ وَلِيَقُولَ ٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ وَٱلۡكَٰفِرُونَ مَاذَآ أَرَادَ ٱللَّهُ بِهَٰذَا مَثَلًاۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِي مَن يَشَآءُۚ وَمَا يَعۡلَمُ جُنُودَ رَبِّكَ إِلَّا هُوَۚ وَمَا هِيَ إِلَّا ذِكۡرَىٰ لِلۡبَشَرِ

Àwa kò ṣe ẹnì kan ní ẹ̀ṣọ́ Iná àfi àwọn mọlāika. Àwa kò sì ṣe òǹkà wọn (bẹ́ẹ̀) bí kò ṣe (nítorí kí ó lè jẹ́) àdánwò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àti nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà lè ní àmọ̀dájú àti nítorí kí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo lè lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo má baà ṣeyèméjì àti nítorí kí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn àti àwọn aláìgbàgbọ́ lè wí pé: "Kí ni Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àpèjúwe yìí?" Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Kò sì sí ẹni tí ó mọ àwọn ọmọ ogun Olúwa rẹ̀ àfi Òun náà. (Iná Saƙọr) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún abara

74:32

كـَلَّا وَٱلۡقَمَرِ

Ẹ gbọ́! Allāhu búra pẹ̀lú òṣùpá

74:33

وَٱلَّيۡلِ إِذۡ أَدۡبَرَ

Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá lọ

74:34

وَٱلصُّبۡحِ إِذَآ أَسۡفَرَ

Ó tún búra pẹ̀lú òwúrọ̀ nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́

74:35

إِنَّهَا لَإِحۡدَى ٱلۡكُبَرِ

Dájúdájú (iná Saƙọr) ni ọ̀kan nínú (àwọn àdánwò) t’ó tóbi

74:36

نَذِيرًا لِّلۡبَشَرِ

(Ó jẹ́) ìkìlọ̀ fún abara

74:37

لِمَن شَآءَ مِنكُمۡ أَن يَتَقَدَّمَ أَوۡ يَتَأَخَّرَ

Fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti tẹ̀ síwájú tàbí láti fà sẹ́yìn

74:38

كُلُّ نَفۡسِۭ بِمَا كَسَبَتۡ رَهِينَةٌ

Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun t’ó ṣe níṣẹ́

74:39

إِلَّآ أَصۡحَٰبَ ٱلۡيَمِينِ

Àyàfi àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún

74:40

فِي جَنَّٰتٍ يَتَسَآءَلُونَ

Wọn yóò máa bira wọn léèrè ọ̀rọ̀ nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra

74:41

عَنِ ٱلۡمُجۡرِمِينَ

nípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pé

74:42

مَا سَلَكَكُمۡ فِي سَقَرَ

Kí ni ó mu yín wọ inú iná Saƙọr

74:43

قَالُواْ لَمۡ نَكُ مِنَ ٱلۡمُصَلِّينَ

Wọn yóò wí pé: "Àwa kò sí nínú àwọn olùkírun ni

74:44

وَلَمۡ نَكُ نُطۡعِمُ ٱلۡمِسۡكِينَ

Àwa kò sì sí nínú àwọn t’ó ń bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù

74:45

وَكُنَّا نَخُوضُ مَعَ ٱلۡخَآئِضِينَ

Àwa sì máa ń sọ ìsọkúsọ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ

74:46

وَكُنَّا نُكَذِّبُ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ

Àti pé àwa máa ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́

74:47

حَتَّىٰٓ أَتَىٰنَا ٱلۡيَقِينُ

títí ikú fi dé bá wa

74:48

فَمَا تَنفَعُهُمۡ شَفَٰعَةُ ٱلشَّٰفِعِينَ

Ìpẹ̀ àwọn olùṣìpẹ̀ kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní

74:49

فَمَا لَهُمۡ عَنِ ٱلتَّذۡكِرَةِ مُعۡرِضِينَ

Kí ló mú wọn ná tí wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí

74:50

كَأَنَّهُمۡ حُمُرٌ مُّسۡتَنفِرَةٌ

bí ẹni pé àwọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ t’ó ń sá lọ

74:51

فَرَّتۡ مِن قَسۡوَرَةِۭ

t’ó sá fún kìnìhún

74:52

بَلۡ يُرِيدُ كُلُّ ٱمۡرِيٍٕ مِّنۡهُمۡ أَن يُؤۡتَىٰ صُحُفًا مُّنَشَّرَةً

Rárá, ńṣe ni ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú wọn ń fẹ́ kí Á fún òun náà ní Tírà tí ó máa ṣeé tẹ́ han àwọn ènìyàn (bíi ti al-Ƙur’ān)

74:53

كـَلَّاۖ بَل لَّا يَخَافُونَ ٱلۡأٓخِرَةَ

Rárá. Wọn kò páyà ọ̀run ni

74:54

كـَلَّآ إِنَّهُۥ تَذۡكِرَةٌ

Ẹ gbọ́! Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí

74:55

فَمَن شَآءَ ذَكَرَهُۥ

Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kó rántí rẹ̀

74:56

وَمَا يَذۡكُرُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُۚ هُوَ أَهۡلُ ٱلتَّقۡوَىٰ وَأَهۡلُ ٱلۡمَغۡفِرَةِ

Wọn kò sì níí rántí (al-Ƙur’ān) àfi tí Allāhu bá fẹ́. (Allāhu) Òun l’a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Òun l’ó sì làforíjìn

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.