Surah 77 · 50 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-Mursalat in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

77:1

وَٱلۡمُرۡسَلَٰتِ عُرۡفًا

Allāhu búra pẹ̀lú àwọn atẹ́gùn t’ó ń sáré ní tẹ̀léǹtẹ̀lé

77:2

فَٱلۡعَٰصِفَٰتِ عَصۡفًا

Ó búra pẹ̀lú àwọn ìjì atẹ́gùn t’ó ń jà

77:3

وَٱلنَّٰشِرَٰتِ نَشۡرًا

Ó búra pẹ̀lú àwọn atẹ́gùn t’ó ń tú èṣújò ká

77:4

فَٱلۡفَٰرِقَٰتِ فَرۡقًا

Ó búra pẹ̀lú àwọn t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́

77:5

فَٱلۡمُلۡقِيَٰتِ ذِكۡرًا

Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń mú ìrántí wá (bá àwọn Òjíṣẹ́)

77:6

عُذۡرًا أَوۡ نُذۡرًا

(Ìrántí náà jẹ́) àwíjàre tàbí ìkìlọ̀

77:7

إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَوَٰقِعٌ

Dájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fun yín kúkú máa ṣẹlẹ̀

77:8

فَإِذَا ٱلنُّجُومُ طُمِسَتۡ

Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́

77:9

وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ فُرِجَتۡ

àti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada

77:10

وَإِذَا ٱلۡجِبَالُ نُسِفَتۡ

àti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù

77:11

وَإِذَا ٱلرُّسُلُ أُقِّتَتۡ

àti nígbà tí wọ́n bá fún àwọn Òjíṣẹ́ ní àsìkò láti kójọ, (Àkókò náà ti dé nìyẹn)

77:12

لِأَيِّ يَوۡمٍ أُجِّلَتۡ

Ọjọ́ wo ni wọ́n so (àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí) rọ̀ fún ná

77:13

لِيَوۡمِ ٱلۡفَصۡلِ

Fún ọjọ́ ìpínyà (láààrin àwọn ẹ̀dá) ni

77:14

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِ

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ìpínyà

77:15

وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

77:16

أَلَمۡ نُهۡلِكِ ٱلۡأَوَّلِينَ

Ǹjẹ́ Àwa kò ti pa àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ́ bí

77:17

ثُمَّ نُتۡبِعُهُمُ ٱلۡأٓخِرِينَ

Lẹ́yìn náà, A sì máa fi àwọn ẹni Ìkẹ́yìn tẹ̀lé wọn (nínú ìparun)

77:18

كَذَٰلِكَ نَفۡعَلُ بِٱلۡمُجۡرِمِينَ

Báyẹn ni A ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀

77:19

وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

77:20

أَلَمۡ نَخۡلُقكُّم مِّن مَّآءٍ مَّهِينٍ

Ṣé A ò ṣẹ̀dá yin láti inú omi lílẹ yẹpẹrẹ bí

77:21

فَجَعَلۡنَٰهُ فِي قَرَارٍ مَّكِينٍ

Lẹ́yìn náà, A fi sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ)

77:22

إِلَىٰ قَدَرٍ مَّعۡلُومٍ

títí di gbèdéke àkókò kan tí A ti mọ̀ (ìyen, ọjọ́ ìbímọ)

77:23

فَقَدَرۡنَا فَنِعۡمَ ٱلۡقَٰدِرُونَ

A sì ní ìkápá àti àyànmọ́ (lórí rẹ̀). (Àwa sì ni) Olùkápá àti Olùpèbùbù ẹ̀dá t’ó dára

77:24

وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

77:25

أَلَمۡ نَجۡعَلِ ٱلۡأَرۡضَ كِفَاتًا

Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ohun t’ó ń kó ẹ̀dá jọ mọ́ra wọn

77:26

أَحۡيَآءً وَأَمۡوَٰتًا

(ìyẹn) àwọn alààyè àti àwọn òkú

77:27

وَجَعَلۡنَا فِيهَا رَوَٰسِيَ شَٰمِخَٰتٍ وَأَسۡقَيۡنَٰكُم مَّآءً فُرَاتًا

A sì fi àwọn àpáta gbagidi gíga-gíga sínú rẹ̀. A sì fun yín ní omi dídùn mu

77:28

وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

77:29

ٱنطَلِقُوٓاْ إِلَىٰ مَا كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ

Ẹ máa lọ sí ibi tí ẹ̀ ń pè nírọ́

77:30

ٱنطَلِقُوٓاْ إِلَىٰ ظِلٍّ ذِي ثَلَٰثِ شُعَبٍ

Ẹ máa lọ sí ibi èéfín ẹlẹ́ka mẹ́ta

77:31

لَّا ظَلِيلٍ وَلَا يُغۡنِي مِنَ ٱللَّهَبِ

Kì í ṣe ibòji tútù. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ìjòfòfò Iná

77:32

إِنَّهَا تَرۡمِي بِشَرَرٍ كَٱلۡقَصۡرِ

Dájúdájú (Iná náà) yóò máa ju ẹ̀tapàrà (rẹ̀ sókè t’ó máa dà) bí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì

77:33

كَأَنَّهُۥ جِمَٰلَتٌ صُفۡرٌ

(Ó máa dà) bí àwọn ràkúnmí aláwọ̀ omi ọsàn

77:34

وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

77:35

هَٰذَا يَوۡمُ لَا يَنطِقُونَ

Èyí ni ọjọ́ tí wọn kò níí sọ̀rọ̀

77:36

وَلَا يُؤۡذَنُ لَهُمۡ فَيَعۡتَذِرُونَ

A ò sì níí yọ̀ǹda (ọ̀rọ̀ sísọ) fún wọn, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò mú àwáwí wá

77:37

وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

77:38

هَٰذَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِۖ جَمَعۡنَٰكُمۡ وَٱلۡأَوَّلِينَ

Èyí ni ọjọ́ ìpínyà. Àwa yó sì kó ẹ̀yin àti àwọn ẹni àkọ́kọ́ jọ

77:39

فَإِن كَانَ لَكُمۡ كَيۡدٌ فَكِيدُونِ

Tí ẹ bá ní ète kan lọ́wọ́, ẹ déte sí Mi wò

77:40

وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

77:41

إِنَّ ٱلۡمُتَّقِينَ فِي ظِلَٰلٍ وَعُيُونٍ

Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà níbi ibòji àti àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú

77:42

وَفَوَٰكِهَ مِمَّا يَشۡتَهُونَ

àti àwọn èso èyí tí wọ́n bá ń fẹ́

77:43

كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ هَنِيٓـَٔۢا بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ

Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbádùn nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

77:44

إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ

Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)

77:45

وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

77:46

كُلُواْ وَتَمَتَّعُواْ قَلِيلًا إِنَّكُم مُّجۡرِمُونَ

Ẹ jẹ, kí ẹ sì gbádùn fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín

77:47

وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

77:48

وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱرۡكَعُواْ لَا يَرۡكَعُونَ

Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé kí wọ́n kírun, wọn kò níí kírun

77:49

وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

77:50

فَبِأَيِّ حَدِيثِۭ بَعۡدَهُۥ يُؤۡمِنُونَ

Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.