Surah 53 · 62 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah An-Najm in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

53:1

وَٱلنَّجۡمِ إِذَا هَوَىٰ

(Allāhu búra pẹ̀lú) ìràwọ̀ nígbà tí ó bá jábọ́

53:2

مَا ضَلَّ صَاحِبُكُمۡ وَمَا غَوَىٰ

Ẹni yín kò ṣìnà, kò sì sọnù

53:3

وَمَا يَنطِقُ عَنِ ٱلۡهَوَىٰٓ

Àti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú

53:4

إِنۡ هُوَ إِلَّا وَحۡيٌ يُوحَىٰ

Kò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i

53:5

عَلَّمَهُۥ شَدِيدُ ٱلۡقُوَىٰ

Alágbára (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) l’ó kọ́ ọ ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān)

53:6

ذُو مِرَّةٍ فَٱسۡتَوَىٰ

Ó ní àlàáfíà t’ó péye. Nítorí náà, ó dúró wámúwámú

53:7

وَهُوَ بِٱلۡأُفُقِ ٱلۡأَعۡلَىٰ

nígbà tí ó wà nínú òfurufú lókè pátápátá

53:8

ثُمَّ دَنَا فَتَدَلَّىٰ

Lẹ́yìn náà, ó sún mọ́ (Ànábì). Ó sì sọ̀kalẹ̀ (tọ̀ ọ́ wá)

53:9

فَكَانَ قَابَ قَوۡسَيۡنِ أَوۡ أَدۡنَىٰ

(Àlàfo ààrin àwọn méjèèjì) sì tó ìwọ̀n ọrún ọfà méjì, tàbí kí ó kéré (sí ìyẹn)

53:10

فَأَوۡحَىٰٓ إِلَىٰ عَبۡدِهِۦ مَآ أَوۡحَىٰ

Allāhu sì fún ẹrúsìn Rẹ̀ ní ìmísí t’Ó fún un

53:11

مَا كَذَبَ ٱلۡفُؤَادُ مَا رَأَىٰٓ

Ọkàn (Ànábì) kò parọ́ ohun t’ó rí

53:12

أَفَتُمَٰرُونَهُۥ عَلَىٰ مَا يَرَىٰ

Ṣé ẹ óò jà á níyàn nípa ohun t’ó rí ni

53:13

وَلَقَدۡ رَءَاهُ نَزۡلَةً أُخۡرَىٰ

Àti pé dájúdájú ó rí i nígbà kejì Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni ó rí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igun yìí fi kún un pé ọkàn l’ó fi rí Allāhu bíi ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀dọ̀ Ọmọ ‘Abbās (rọdiyallāhu 'anhu) wá pé “Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi ọkàn rẹ̀ rí Allāhu ni.” Ìyẹn ni pé

53:14

عِندَ سِدۡرَةِ ٱلۡمُنتَهَىٰ

níbi igi sidirah al-Muntahā

53:15

عِندَهَا جَنَّةُ ٱلۡمَأۡوَىٰٓ

nítòsí rẹ̀ ni Ọgbà Ibùgbé (gbére) wà

53:16

إِذۡ يَغۡشَى ٱلسِّدۡرَةَ مَا يَغۡشَىٰ

(Rántí) nígbà tí ohun t’ó bo igi Sidirah bò ó mọ́lẹ̀

53:17

مَا زَاغَ ٱلۡبَصَرُ وَمَا طَغَىٰ

Ojú (Ànábì) kò yẹ̀, kò sì tayọ ẹnu-àlà

53:18

لَقَدۡ رَأَىٰ مِنۡ ءَايَٰتِ رَبِّهِ ٱلۡكُبۡرَىٰٓ

Dájúdájú ó rí nínú àwọn àmì Olúwa rẹ̀, t’ó tóbi jùlọ

53:19

أَفَرَءَيۡتُمُ ٱللَّٰتَ وَٱلۡعُزَّىٰ

Ẹ sọ fún mi nípa òrìṣà Lāt àti òrìṣà ‘Uzzā

53:20

وَمَنَوٰةَ ٱلثَّالِثَةَ ٱلۡأُخۡرَىٰٓ

àti Mọnāh, òrìṣà kẹta mìíràn

53:21

أَلَكُمُ ٱلذَّكَرُ وَلَهُ ٱلۡأُنثَىٰ

Ṣé ọmọkùnrin ni tiyín, ọmọbìnrin sì ni tiRẹ̀

53:22

تِلۡكَ إِذًا قِسۡمَةٌ ضِيزَىٰٓ

Ìpín àbòsí nìyẹn nígbà náà

53:23

إِنۡ هِيَ إِلَّآ أَسۡمَآءٌ سَمَّيۡتُمُوهَآ أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ بِهَا مِن سُلۡطَٰنٍۚ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّ وَمَا تَهۡوَى ٱلۡأَنفُسُۖ وَلَقَدۡ جَآءَهُم مِّن رَّبِّهِمُ ٱلۡهُدَىٰٓ

(Àwọn orúkọ òrìṣà wọ̀nyẹn) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín fi sọ (àwọn òrìṣà yín fúnra yín). Allāhu kò sì sọ ẹ̀rí ọ̀rọ̀ kan kalẹ̀ nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ àti ohun tí ẹ̀mí (wọn) ń fẹ́. Ìmọ̀nà kúkú ti dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn

53:24

أَمۡ لِلۡإِنسَٰنِ مَا تَمَنَّىٰ

Tàbí ti ènìyàn ni n̄ǹkan t’ó bá ń fẹ́

53:25

فَلِلَّهِ ٱلۡأٓخِرَةُ وَٱلۡأُولَىٰ

Ti Allāhu sì ni ọ̀run àti ayé

53:26

وَكَم مِّن مَّلَكٍ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ لَا تُغۡنِي شَفَٰعَتُهُمۡ شَيۡـًٔا إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ أَن يَأۡذَنَ ٱللَّهُ لِمَن يَشَآءُ وَيَرۡضَىٰٓ

Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn mọlāika t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀, tí ìṣìpẹ̀ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan àyàfi lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu bá yọ̀ǹda fún ẹni tí Ó bá fẹ́, tí Ó sì yọ́nú sí

53:27

إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ لَيُسَمُّونَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ تَسۡمِيَةَ ٱلۡأُنثَىٰ

Dájúdájú àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn ni wọ́n ń fún àwọn mọlāika ní orúkọ obìnrin

53:28

وَمَا لَهُم بِهِۦ مِنۡ عِلۡمٍۖ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّۖ وَإِنَّ ٱلظَّنَّ لَا يُغۡنِي مِنَ ٱلۡحَقِّ شَيۡـًٔا

Kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ. Dájúdájú àròsọ kò sì níí rọrọ̀ kiní kan lára òdodo

53:29

فَأَعۡرِضۡ عَن مَّن تَوَلَّىٰ عَن ذِكۡرِنَا وَلَمۡ يُرِدۡ إِلَّا ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا

Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ ẹni t’ó kẹ̀yìn sí ìrántí Wa, tí kò sì gbèrò kiní kan àfi ìṣẹ̀mí ayé

53:30

ذَٰلِكَ مَبۡلَغُهُم مِّنَ ٱلۡعِلۡمِۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِمَنِ ٱهۡتَدَىٰ

Ìyẹn ni òdíwọ̀n (àti òpin) ìmọ̀ wọn. Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó mọ̀nà

53:31

وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ لِيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ أَسَٰٓـُٔواْ بِمَا عَمِلُواْ وَيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ بِٱلۡحُسۡنَى

Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ nítorí kí Ó lè san àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti nítorí kí Ó lè san àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ rere ni ẹ̀san rere

53:32

ٱلَّذِينَ يَجۡتَنِبُونَ كَبَٰٓئِرَ ٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡفَوَٰحِشَ إِلَّا ٱللَّمَمَۚ إِنَّ رَبَّكَ وَٰسِعُ ٱلۡمَغۡفِرَةِۚ هُوَ أَعۡلَمُ بِكُمۡ إِذۡ أَنشَأَكُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ وَإِذۡ أَنتُمۡ أَجِنَّةٌ فِي بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمۡۖ فَلَا تُزَكُّوٓاْ أَنفُسَكُمۡۖ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَنِ ٱتَّقَىٰٓ

Àwọn t’ó ń jìnnà sí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá àti ìwà ìbàjẹ́ àyàfi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, dájúdájú Olúwa rẹ gbòòrò ní àforíjìn. Ó nímọ̀ jùlọ nípa yín nígbà tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú ilẹ̀ àti nígbà tí ẹ wà ní ọlẹ̀ nínú àwọn ikùn ìyá yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe fọra yín mọ́. Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀)

53:33

أَفَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي تَوَلَّىٰ

Sọ fún mi nípa ẹni t’ó gbúnrí (kúrò níbi òdodo)

53:34

وَأَعۡطَىٰ قَلِيلًا وَأَكۡدَىٰٓ

tí ó fi díẹ̀ tọrẹ, tí ó sì di ìyókù mọ́wọ́

53:35

أَعِندَهُۥ عِلۡمُ ٱلۡغَيۡبِ فَهُوَ يَرَىٰٓ

Ṣé ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà ní ọ̀dọ̀ rẹ, tí ó sì ń rí i (pé ẹlòmíìràn l’ó ma bá òun jìyà lọ́run)

53:36

أَمۡ لَمۡ يُنَبَّأۡ بِمَا فِي صُحُفِ مُوسَىٰ

Tàbí wọn kò fún un ní ìró ohun t’ó wà nínú tírà (Ànábì) Mūsā ni

53:37

وَإِبۡرَٰهِيمَ ٱلَّذِي وَفَّىٰٓ

àti (tírà Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ẹni t’ó mú (òfin Allāhu) ṣẹ

53:38

أَلَّا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزۡرَ أُخۡرَىٰ

pé dájúdájú ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù-ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn

53:39

وَأَن لَّيۡسَ لِلۡإِنسَٰنِ إِلَّا مَا سَعَىٰ

Àti pé kò sí kiní kan fún ènìyàn àfi ohun t’ó ṣe níṣẹ́

53:40

وَأَنَّ سَعۡيَهُۥ سَوۡفَ يُرَىٰ

Àti pé dájúdájú iṣẹ́ rẹ̀, láìpẹ́ wọ́n máa fi hàn án

53:41

ثُمَّ يُجۡزَىٰهُ ٱلۡجَزَآءَ ٱلۡأَوۡفَىٰ

Lẹ́yìn náà, wọ́n máa san án ní ẹ̀san rẹ̀, ní ẹ̀san t’ó kún jùlọ

53:42

وَأَنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلۡمُنتَهَىٰ

Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin (ìrìn-àjò ẹ̀dá)

53:43

وَأَنَّهُۥ هُوَ أَضۡحَكَ وَأَبۡكَىٰ

Dájúdájú Òun l’Ó ń pa (ẹ̀dá) ní ẹ̀rín. Ó sì ń pa (ẹ̀dá) ní ẹkún

53:44

وَأَنَّهُۥ هُوَ أَمَاتَ وَأَحۡيَا

Dájúdájú Òun l’Ó ń sọ (ẹ̀dá) di òkú. Ó sì ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè

53:45

وَأَنَّهُۥ خَلَقَ ٱلزَّوۡجَيۡنِ ٱلذَّكَرَ وَٱلۡأُنثَىٰ

Dájúdájú Òun l’Ó dá ẹ̀dá ní oríṣi méjì, ọkùnrin àti obìnrin

53:46

مِن نُّطۡفَةٍ إِذَا تُمۡنَىٰ

láti ara àtọ̀ nígbà tí wọ́n bá dà á sínú àpòlùkẹ́

53:47

وَأَنَّ عَلَيۡهِ ٱلنَّشۡأَةَ ٱلۡأُخۡرَىٰ

Dájúdájú Òun l’Ó máa ṣe ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn fún àjíǹde

53:48

وَأَنَّهُۥ هُوَ أَغۡنَىٰ وَأَقۡنَىٰ

Dájúdájú Òun l’Ó ń ṣe púpọ̀, Ó sì ń ṣe kékeré (oore fún ẹ̀dá)

53:49

وَأَنَّهُۥ هُوَ رَبُّ ٱلشِّعۡرَىٰ

Dájúdájú Òun sì ni Olúwa ìràwọ̀ Ṣi‘rọ̄ (tí wọ́n sọ di òrìṣà)

53:50

وَأَنَّهُۥٓ أَهۡلَكَ عَادًا ٱلۡأُولَىٰ

Dájúdájú Òun l’Ó pa ìran ‘Ād rẹ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́

53:51

وَثَمُودَاْ فَمَآ أَبۡقَىٰ

àti ìran Thamūd, kò sì ṣẹ́ wọn kù

53:52

وَقَوۡمَ نُوحٍ مِّن قَبۡلُۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ هُمۡ أَظۡلَمَ وَأَطۡغَىٰ

àti ìjọ Nūh t’ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ alábòsí jùlọ, wọ́n sì tayọ ẹnu-àlà jùlọ

53:53

وَٱلۡمُؤۡتَفِكَةَ أَهۡوَىٰ

àti ìlú tí wọ́n dàwó (ìlú Ànábì Lūt) t’Ó yẹ̀ lulẹ̀ (láti òkè)

53:54

فَغَشَّىٰهَا مَا غَشَّىٰ

Ohun t’ó bò wọ́n mọ́lẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀

53:55

فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكَ تَتَمَارَىٰ

Nítorí náà, èwo nínú ìdẹ̀ra Olúwa rẹ ni ìwọ (ènìyàn) ń jà níyàn

53:56

هَٰذَا نَذِيرٌ مِّنَ ٱلنُّذُرِ ٱلۡأُولَىٰٓ

Èyí ni ìkìlọ̀ kan nínú àwọn ìkìlọ̀ àkọ́kọ́

53:57

أَزِفَتِ ٱلۡأٓزِفَةُ

Ohun t’ó súnmọ́ súnmọ́

53:58

لَيۡسَ لَهَا مِن دُونِ ٱللَّهِ كَاشِفَةٌ

Lẹ́yìn Allāhu, kò sí ẹni t’ó lè ṣàfi hàn (Àkókò náà)

53:59

أَفَمِنۡ هَٰذَا ٱلۡحَدِيثِ تَعۡجَبُونَ

Ṣé ọ̀rọ̀ yìí l’ó ń ṣe yín ní kàyéfì

53:60

وَتَضۡحَكُونَ وَلَا تَبۡكُونَ

Ẹ̀ ń rẹ́rìn-ín, ẹ ò sì sunkún

53:61

وَأَنتُمۡ سَٰمِدُونَ

Afọ́nú-fọ́ra ni yín

53:62

فَٱسۡجُدُواْۤ لِلَّهِۤ وَٱعۡبُدُواْ

Nítorí náà, ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, kí ẹ jọ́sìn (fún Un)

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.