Surah 69 · 52 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-Haqqah in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

69:1

ٱلۡحَآقَّةُ

Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo

69:2

مَا ٱلۡحَآقَّةُ

Kí ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo

69:3

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡحَآقَّةُ

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo

69:4

كَذَّبَتۡ ثَمُودُ وَعَادُۢ بِٱلۡقَارِعَةِ

Àwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Ìpáyà nírọ́

69:5

فَأَمَّا ثَمُودُ فَأُهۡلِكُواْ بِٱلطَّاغِيَةِ

Ní ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe t’ó tayọ ẹnu-àlà pa wọ́n rẹ́

69:6

وَأَمَّا عَادٌ فَأُهۡلِكُواْ بِرِيحٍ صَرۡصَرٍ عَاتِيَةٍ

Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n fi atẹ́gùn líle t’ó tayọ ẹnu-àlà pa wọ́n rẹ́

69:7

سَخَّرَهَا عَلَيۡهِمۡ سَبۡعَ لَيَالٍ وَثَمَٰنِيَةَ أَيَّامٍ حُسُومًاۖ فَتَرَى ٱلۡقَوۡمَ فِيهَا صَرۡعَىٰ كَأَنَّهُمۡ أَعۡجَازُ نَخۡلٍ خَاوِيَةٍ

Ó dẹ ẹ́ sí wọn fún òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ láì dáwọ́ dúró. O sì máa rí ìjọ náà tí wọ́n ti kú sínú rẹ̀ bí ẹni pé kùkùté igi dàbínù t’ó ti luhò nínú ni wọ́n

69:8

فَهَلۡ تَرَىٰ لَهُم مِّنۢ بَاقِيَةٍ

Ǹjẹ́ o rí ẹnì kan nínú wọn t’ó ṣẹ́ kù bí

69:9

وَجَآءَ فِرۡعَوۡنُ وَمَن قَبۡلَهُۥ وَٱلۡمُؤۡتَفِكَٰتُ بِٱلۡخَاطِئَةِ

Fir‘aon àti àwọn t’ó ṣíwájú rẹ̀ àti àwọn ìlú tí wọ́n dojú rẹ̀ bolẹ̀ dé pẹ̀lú àwọn àṣìṣe

69:10

فَعَصَوۡاْ رَسُولَ رَبِّهِمۡ فَأَخَذَهُمۡ أَخۡذَةً رَّابِيَةً

Wọ́n yapa Òjíṣẹ́ Olúwa wọn. Ó sì gbá wọn mú ní ìgbámú àlékún

69:11

إِنَّا لَمَّا طَغَا ٱلۡمَآءُ حَمَلۡنَٰكُمۡ فِي ٱلۡجَارِيَةِ

Dájúdájú nígbà tí omi tayọ ẹnu-àlà. A gbe yín gun ọkọ̀ ojú-omi

69:12

لِنَجۡعَلَهَا لَكُمۡ تَذۡكِرَةً وَتَعِيَهَآ أُذُنٌ وَٰعِيَةٌ

Nítorí kí Á lè fi ṣe ìrántí fun yín àti nítorí kí etí t’ó ń ṣọ́ n̄ǹkan lè ṣọ́ ọ

69:13

فَإِذَا نُفِخَ فِي ٱلصُّورِ نَفۡخَةٌ وَٰحِدَةٌ

Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún ikú ní fífọn ẹyọ kan

69:14

وَحُمِلَتِ ٱلۡأَرۡضُ وَٱلۡجِبَالُ فَدُكَّتَا دَكَّةً وَٰحِدَةً

tí wọ́n gbé ilẹ̀ àti àpáta sókè, tí wọ́n sì rún méjèèjì wómúwómú ní rírún ẹ̀ẹ̀ kan

69:15

فَيَوۡمَئِذٍ وَقَعَتِ ٱلۡوَاقِعَةُ

ní ọjọ́ yẹn ni Ìṣẹ̀lẹ̀ máa ṣẹlẹ̀

69:16

وَٱنشَقَّتِ ٱلسَّمَآءُ فَهِيَ يَوۡمَئِذٍ وَاهِيَةٌ

Àti pé sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó sì máa fúyẹ́ gẹgẹ ní ọjọ́ yẹn

69:17

وَٱلۡمَلَكُ عَلَىٰٓ أَرۡجَآئِهَاۚ وَيَحۡمِلُ عَرۡشَ رَبِّكَ فَوۡقَهُمۡ يَوۡمَئِذٍ ثَمَٰنِيَةٌ

Àwọn mọlāika sì máa wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àti pé ní ọjọ́ yẹn, lókè wọn, àwọn (mọlāika) mẹ́jọ ni wọ́n máa ru Ìtẹ́ Olúwa rẹ

69:18

يَوۡمَئِذٍ تُعۡرَضُونَ لَا تَخۡفَىٰ مِنكُمۡ خَافِيَةٌ

Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò máa ṣẹ́rí yín wá (fún ìṣírò-iṣẹ́). Kò sì níí sí àṣírí yín kan t’ó máa pamọ́ (fún Wa)

69:19

فَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِيَمِينِهِۦ فَيَقُولُ هَآؤُمُ ٱقۡرَءُواْ كِتَٰبِيَهۡ

Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó máa sọ pé: "Ẹ gbà, ẹ ka tírà mi

69:20

إِنِّي ظَنَنتُ أَنِّي مُلَٰقٍ حِسَابِيَهۡ

Dájúdájú èmi ti mọ àmọ̀dájú pé dájúdájú èmi yóò bá ìṣírò-iṣẹ́ mi pàdé

69:21

فَهُوَ فِي عِيشَةٍ رَّاضِيَةٍ

Nítorí náà, ó máa wà nínú ìṣẹ̀mí t’ó máa yọ́nú sí

69:22

فِي جَنَّةٍ عَالِيَةٍ

nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga

69:23

قُطُوفُهَا دَانِيَةٌ

Àwọn èso rẹ̀ (sì) wà ní àrọ́wọ́tó

69:24

كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ هَنِيٓـَٔۢا بِمَآ أَسۡلَفۡتُمۡ فِي ٱلۡأَيَّامِ ٱلۡخَالِيَةِ

Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbàdún nítorí ohun tí ẹ tì síwájú nínú àwọn ọjọ́ tí ó ti ré kọjá

69:25

وَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِشِمَالِهِۦ فَيَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي لَمۡ أُوتَ كِتَٰبِيَهۡ

Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ó máa wí pé: "Háà! Kí wọ́n sì má fún mi ni tírà mi! méjéèjì ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí pé ọwọ́ òsì ni aláìgbàgbọ́ máa tì bọ inú igbá-àyà rẹ̀ bọ́ sí ẹ̀yìn rẹ̀ láti fi gba ìwé iṣẹ́ rẹ̀

69:26

وَلَمۡ أَدۡرِ مَا حِسَابِيَهۡ

Àti pé èmi kò mọ ohun tí ìṣírò-iṣẹ́ mi jẹ́

69:27

يَٰلَيۡتَهَا كَانَتِ ٱلۡقَاضِيَةَ

Háà! Kí ikú sì jẹ́ òpin (ọ̀rọ̀ ẹ̀dá)

69:28

مَآ أَغۡنَىٰ عَنِّي مَالِيَهۡۜ

Dúkìá mi kò sì rọ̀ mí lọ́rọ̀

69:29

هَلَكَ عَنِّي سُلۡطَٰنِيَهۡ

Agbára mi sì ti parun

69:30

خُذُوهُ فَغُلُّوهُ

Ẹ mú un, kí ẹ dè é ní ọwọ́ mọ́ ọrùn

69:31

ثُمَّ ٱلۡجَحِيمَ صَلُّوهُ

Lẹ́yìn náà, inú iná Jẹhīm ni kí ẹ mú un wọ̀

69:32

ثُمَّ فِي سِلۡسِلَةٍ ذَرۡعُهَا سَبۡعُونَ ذِرَاعًا فَٱسۡلُكُوهُ

Lẹ́yìn náà, inú ẹ̀wọ̀n tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin gígùn thar‘u ni kí ẹ kì í sí

69:33

إِنَّهُۥ كَانَ لَا يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ ٱلۡعَظِيمِ

Dájúdájú òun kì í gbàgbọ́ nínú Allāhu, Atóbi

69:34

وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ

Kì í sì gba ènìyàn níyànjú láti bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù

69:35

فَلَيۡسَ لَهُ ٱلۡيَوۡمَ هَٰهُنَا حَمِيمٌ

Nítorí náà, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan fún un níbí yìí ní òní

69:36

وَلَا طَعَامٌ إِلَّا مِنۡ غِسۡلِينٍ

Kò sì níí sí oúnjẹ kan (fún un) bí kò ṣe (oúnjẹ) àwọyúnwẹ̀jẹ̀

69:37

لَّا يَأۡكُلُهُۥٓ إِلَّا ٱلۡخَٰطِـُٔونَ

Kò sí ẹni tí ó máa jẹ ẹ́ bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀

69:38

فَلَآ أُقۡسِمُ بِمَا تُبۡصِرُونَ

Nítorí náà, Èmi ń búra pẹ̀lú ohun tí ẹ̀ ń fojú rí

69:39

وَمَا لَا تُبۡصِرُونَ

àti ohun tí ẹ ò fojú rí

69:40

إِنَّهُۥ لَقَوۡلُ رَسُولٍ كَرِيمٍ

Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé

69:41

وَمَا هُوَ بِقَوۡلِ شَاعِرٍۚ قَلِيلًا مَّا تُؤۡمِنُونَ

Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eléwì. Ohun tí ẹ gbàgbọ́ kéré púpọ̀

69:42

وَلَا بِقَوۡلِ كَاهِنٍۚ قَلِيلًا مَّا تَذَكَّرُونَ

Kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ adábigba. Díẹ̀ lẹ̀ ń lò nínú ìrántí

69:43

تَنزِيلٌ مِّن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

69:44

وَلَوۡ تَقَوَّلَ عَلَيۡنَا بَعۡضَ ٱلۡأَقَاوِيلِ

Tí ó bá jẹ́ pé (Ànábì) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni

69:45

لَأَخَذۡنَا مِنۡهُ بِٱلۡيَمِينِ

Àwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún

69:46

ثُمَّ لَقَطَعۡنَا مِنۡهُ ٱلۡوَتِينَ

Lẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀

69:47

فَمَا مِنكُم مِّنۡ أَحَدٍ عَنۡهُ حَٰجِزِينَ

Kò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa)

69:48

وَإِنَّهُۥ لَتَذۡكِرَةٌ لِّلۡمُتَّقِينَ

Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

69:49

وَإِنَّا لَنَعۡلَمُ أَنَّ مِنكُم مُّكَذِّبِينَ

Dájúdájú Àwa sì mọ̀ pé àwọn t’ó ń pe al-Ƙur’ān nírọ́ wà nínú yín

69:50

وَإِنَّهُۥ لَحَسۡرَةٌ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ

Dájúdájú al-Ƙur’ān máa jẹ́ àbámọ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́

69:51

وَإِنَّهُۥ لَحَقُّ ٱلۡيَقِينِ

Dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo t’ó dájú

69:52

فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ

Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa Rẹ, Atóbi

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.