Surah 51 · 60 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Adh-Dhariyat in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

51:1

وَٱلذَّٰرِيَٰتِ ذَرۡوًا

(Allāhu búra pẹ̀lú) atẹ́gùn t’ó ń tu erùpẹ̀ jáde nílẹ̀ tààrà

51:2

فَٱلۡحَٰمِلَٰتِ وِقۡرًا

(Ó búra pẹ̀lú) àwọn ẹ̀ṣújò t’ó wúwo rinrin

51:3

فَٱلۡجَٰرِيَٰتِ يُسۡرًا

(Ó búra pẹ̀lú) àwọn ọkọ̀ ojú-omi t’ó ń rìn pẹ̀lú ìrọ̀rùn

51:4

فَٱلۡمُقَسِّمَٰتِ أَمۡرًا

(Ó búra pẹ̀lú) àwọn mọlāika t’ó ń pín n̄ǹkan (tí Ó ti pín fún ẹ̀dá)

51:5

إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَصَادِقٌ

Òdodo mà ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín

51:6

وَإِنَّ ٱلدِّينَ لَوَٰقِعٌ

Àti pé dájúdájú Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀

51:7

وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلۡحُبُكِ

(Allāhu tún búra pẹ̀lú) sánmọ̀ ọlọ́ṣọ̀ọ́

51:8

إِنَّكُمۡ لَفِي قَوۡلٍ مُّخۡتَلِفٍ

Dájúdájú ẹ̀yin wà lórí ọ̀rọ̀ t’ó ń takora wọn (nípa al-Ƙur’ān)

51:9

يُؤۡفَكُ عَنۡهُ مَنۡ أُفِكَ

Ẹni tí wọ́n ń ṣẹ́ lórí kúrò níbi al-Ƙur’ān ni ẹni tí Wọ́n ti ṣẹ́ lórí kúrò níbẹ̀ (láti inú Laohul-Mahfūṭḥ)

51:10

قُتِلَ ٱلۡخَرَّٰصُونَ

Ègbé ni fún àwọn òpùrọ́

51:11

ٱلَّذِينَ هُمۡ فِي غَمۡرَةٍ سَاهُونَ

àwọn ni wọ́n wà nínú àìmọ̀kan, àwọn onígbàgbé

51:12

يَسۡـَٔلُونَ أَيَّانَ يَوۡمُ ٱلدِّينِ

tí wọ́n ń bèèrè ìgbà tí Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀

51:13

يَوۡمَ هُمۡ عَلَى ٱلنَّارِ يُفۡتَنُونَ

Ní ọjọ́ náà sì ni wọn yóò máa fi Iná jẹ wọ́n níyà

51:14

ذُوقُواْ فِتۡنَتَكُمۡ هَٰذَا ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تَسۡتَعۡجِلُونَ

Ẹ tọ́ ìyà yín wò. Èyí ni n̄ǹkan tí ẹ ti ń wá pẹ̀lú ìkánjú

51:15

إِنَّ ٱلۡمُتَّقِينَ فِي جَنَّٰتٍ وَعُيُونٍ

Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi odò (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀)

51:16

ءَاخِذِينَ مَآ ءَاتَىٰهُمۡ رَبُّهُمۡۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَبۡلَ ذَٰلِكَ مُحۡسِنِينَ

Wọn yóò máa gba n̄ǹkan tí Olúwa wọn bá fún wọn. Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ olùṣe-rere ṣíwájú ìyẹn

51:17

كَانُواْ قَلِيلًا مِّنَ ٱلَّيۡلِ مَا يَهۡجَعُونَ

Wọ́n máa ń sun oorun díẹ̀ nínú òru

51:18

وَبِٱلۡأَسۡحَارِ هُمۡ يَسۡتَغۡفِرُونَ

Wọ́n máa ń tọrọ àforíjìn ní àfẹ̀mọ́júmọ́

51:19

وَفِيٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ حَقٌّ لِّلسَّآئِلِ وَٱلۡمَحۡرُومِ

Nínú dúkìá wọn, wọ́n ní ojúṣe tí wọ́n ń ṣe fún alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún

51:20

وَفِي ٱلۡأَرۡضِ ءَايَٰتٌ لِّلۡمُوقِنِينَ

Àwọn àmì wà ní orí ilẹ̀ fún àwọn alámọ̀dájú

51:21

وَفِيٓ أَنفُسِكُمۡۚ أَفَلَا تُبۡصِرُونَ

Nínú ẹ̀mí ara yín gan-an (àmì ìyanu wà nínú rẹ̀). Ṣé ẹ ò ríran ni

51:22

وَفِي ٱلسَّمَآءِ رِزۡقُكُمۡ وَمَا تُوعَدُونَ

Arísìkí yín àti ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín wà nínú sánmọ̀

51:23

فَوَرَبِّ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِ إِنَّهُۥ لَحَقٌّ مِّثۡلَ مَآ أَنَّكُمۡ تَنطِقُونَ

Nítorí náà, Mó fi Olúwa sánmọ̀ àti ilẹ̀ búra, dájúdájú òdodo ni (ọ̀rọ̀ náà) gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ òdodo pé ẹ̀ ń fẹnu sọ̀rọ̀

51:24

هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ضَيۡفِ إِبۡرَٰهِيمَ ٱلۡمُكۡرَمِينَ

Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, ti dé ọ̀dọ̀ rẹ

51:25

إِذۡ دَخَلُواْ عَلَيۡهِ فَقَالُواْ سَلَٰمًاۖ قَالَ سَلَٰمٌ قَوۡمٌ مُّنكَرُونَ

(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì sọ pé: "Àlàáfíà (fún ọ)." Òun náà sọ pé: "Àlàáfíà (fun yín), ẹ̀yin àjòjì ènìyàn

51:26

فَرَاغَ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ فَجَآءَ بِعِجۡلٍ سَمِينٍ

Ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, ó sì dé pẹ̀lú ọmọ màálù ọlọ́ràá (àyangbẹ)

51:27

فَقَرَّبَهُۥٓ إِلَيۡهِمۡ قَالَ أَلَا تَأۡكُلُونَ

Ó gbé e súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn. Ó sì sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí jẹun ni

51:28

فَأَوۡجَسَ مِنۡهُمۡ خِيفَةًۖ قَالُواْ لَا تَخَفۡۖ وَبَشَّرُوهُ بِغُلَٰمٍ عَلِيمٍ

Nígbà náà, ó ní ìpáyà wọn nínú ọkàn. Wọ́n sọ pé: "Má ṣe páyà." Wọ́n sì fún un ní ìró ìdùnnú nípa bíbí ọmọkùnrin onímọ̀ kan

51:29

فَأَقۡبَلَتِ ٱمۡرَأَتُهُۥ فِي صَرَّةٍ فَصَكَّتۡ وَجۡهَهَا وَقَالَتۡ عَجُوزٌ عَقِيمٌ

Nígbà náà, ìyàwó rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ igbe, ó sì gbára rẹ̀ lójú, ó sọ pé: "Arúgbó, àgàn (mà ni mí)

51:30

قَالُواْ كَذَٰلِكِ قَالَ رَبُّكِۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡحَكِيمُ ٱلۡعَلِيمُ

Wọ́n sọ pé: "Báyẹn ni Olúwa rẹ sọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀

51:31

قَالَ فَمَا خَطۡبُكُمۡ أَيُّهَا ٱلۡمُرۡسَلُونَ

(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: "Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́

51:32

قَالُوٓاْ إِنَّآ أُرۡسِلۡنَآ إِلَىٰ قَوۡمٍ مُّجۡرِمِينَ

Wọ́n sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni

51:33

لِنُرۡسِلَ عَلَيۡهِمۡ حِجَارَةً مِّن طِينٍ

nítorí kí á lè fi òkúta amọ̀ (sísun) ránṣẹ́ sí wọn

51:34

مُّسَوَّمَةً عِندَ رَبِّكَ لِلۡمُسۡرِفِينَ

Wọ́n ti fàmì sí i lára lọ́dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn alákọyọ

51:35

فَأَخۡرَجۡنَا مَن كَانَ فِيهَا مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Nítorí náà, A mú àwọn t’ó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo jáde kúrò nínú (ìlú náà)

51:36

فَمَا وَجَدۡنَا فِيهَا غَيۡرَ بَيۡتٍ مِّنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ

A ò sì rí nínú (ìlú náà) tayọ ilé kan t’ó jẹ́ ti àwọn mùsùlùmí

51:37

وَتَرَكۡنَا فِيهَآ ءَايَةً لِّلَّذِينَ يَخَافُونَ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَلِيمَ

A sì fi àmì kan sílẹ̀ nínú (ìlú náà) fún àwọn t’ó ń páyà ìyà ẹlẹ́ta-eléro

51:38

وَفِي مُوسَىٰٓ إِذۡ أَرۡسَلۡنَٰهُ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ بِسُلۡطَٰنٍ مُّبِينٍ

(Àmì tún wà) lára (Ànábì) Mūsā. Nígbà tí A fi ẹ̀rí pọ́nńbélé rán an níṣẹ́ sí Fir‘aon

51:39

فَتَوَلَّىٰ بِرُكۡنِهِۦ وَقَالَ سَٰحِرٌ أَوۡ مَجۡنُونٌ

Ṣùgbọ́n (Fir‘aon) gbúnrí pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó sì wí pé: "Òpìdán tàbí wèrè kan (nìyí)

51:40

فَأَخَذۡنَٰهُ وَجُنُودَهُۥ فَنَبَذۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡيَمِّ وَهُوَ مُلِيمٌ

Nítorí náà, A mú òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. A sì jù wọ́n sínú agbami odò nígbà tí ó jẹ́ alábùkù

51:41

وَفِي عَادٍ إِذۡ أَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمُ ٱلرِّيحَ ٱلۡعَقِيمَ

(Àmì tún wà) lára ìjọ ‘Ād. (Rántí) nígbà tí A rán atẹ́gùn ìparun sí wọn

51:42

مَا تَذَرُ مِن شَيۡءٍ أَتَتۡ عَلَيۡهِ إِلَّا جَعَلَتۡهُ كَٱلرَّمِيمِ

kò fi kiní kan tó fẹ́ sí lára sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ àfi kó sọ ọ́ di bí èso rírún túútú

51:43

وَفِي ثَمُودَ إِذۡ قِيلَ لَهُمۡ تَمَتَّعُواْ حَتَّىٰ حِينٍ

(Àmì tún wà) lára ìjọ Thamūd. (Rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: "Ẹ jayé fún ìgbà díẹ̀ ná

51:44

فَعَتَوۡاْ عَنۡ أَمۡرِ رَبِّهِمۡ فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلصَّٰعِقَةُ وَهُمۡ يَنظُرُونَ

Wọ́n ṣègbéraga sí àṣẹ Olúwa wọn. Nítorí náà, igbe ìparun mú wọ́n; wọ́n sì ń wò bọ̀ọ̀

51:45

فَمَا ٱسۡتَطَٰعُواْ مِن قِيَامٍ وَمَا كَانُواْ مُنتَصِرِينَ

Wọn kò lè dìde nàró. Wọn kò sì lè ran ara wọn lọ́wọ́

51:46

وَقَوۡمَ نُوحٍ مِّن قَبۡلُۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمًا فَٰسِقِينَ

Àti ìjọ Nūh tí ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú Àwa sì ni olùgbòòrò

51:47

وَٱلسَّمَآءَ بَنَيۡنَٰهَا بِأَيۡيْدٍ وَإِنَّا لَمُوسِعُونَ

Àti pé sánmọ̀, A mọ ọ́n (sí òkè yín) pẹ̀lú agbára. Dájúdájú Àwa sì ni olùgbòòrò

51:48

وَٱلۡأَرۡضَ فَرَشۡنَٰهَا فَنِعۡمَ ٱلۡمَٰهِدُونَ

Àti ilẹ̀, A ṣe é ní ìtẹ́. Àwọn olùtẹ́lẹ̀-sílẹ̀ sì dára

51:49

وَمِن كُلِّ شَيۡءٍ خَلَقۡنَا زَوۡجَيۡنِ لَعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ

Àti pé gbogbo n̄ǹkan ni A ṣẹ̀dá ní oríṣi méjì-méjì nítorí kí ẹ lè lo ìrántí

51:50

فَفِرُّوٓاْ إِلَى ٱللَّهِۖ إِنِّي لَكُم مِّنۡهُ نَذِيرٌ مُّبِينٌ

Nítorí náà, ẹ sá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀

51:51

وَلَا تَجۡعَلُواْ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَۖ إِنِّي لَكُم مِّنۡهُ نَذِيرٌ مُّبِينٌ

Ẹ má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀

51:52

كَذَٰلِكَ مَآ أَتَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا قَالُواْ سَاحِرٌ أَوۡ مَجۡنُونٌ

Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ ṣe rí)! Òjíṣẹ́ kan kò wá bá àwọn t’ó ṣíwájú wọn àfi kí wọ́n wí pé: "Òpìdán tàbí wèrè ni

51:53

أَتَوَاصَوۡاْ بِهِۦۚ بَلۡ هُمۡ قَوۡمٌ طَاغُونَ

Ṣé wọn sọ àsọọ́lẹ̀ nípa rẹ̀ láààrin ara wọn ni? Rárá o! Ìjọ olùtayọ-ẹnu-àlà ni wọ́n ni

51:54

فَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ فَمَآ أَنتَ بِمَلُومٍ

Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn ná. Ìwọ kì í ṣe alábùkù

51:55

وَذَكِّرۡ فَإِنَّ ٱلذِّكۡرَىٰ تَنفَعُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Ṣèrántí nítorí pé, dájúdájú ìrántí máa wúlò fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

51:56

وَمَا خَلَقۡتُ ٱلۡجِنَّ وَٱلۡإِنسَ إِلَّا لِيَعۡبُدُونِ

Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi

51:57

مَآ أُرِيدُ مِنۡهُم مِّن رِّزۡقٍ وَمَآ أُرِيدُ أَن يُطۡعِمُونِ

Èmi kò gbèrò arísìkí kan láti ọ̀dọ̀ wọn. Èmi kò sì gbèrò pé kí wọ́n máa bọ́ Mi

51:58

إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلرَّزَّاقُ ذُو ٱلۡقُوَّةِ ٱلۡمَتِينُ

Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùpèsè, Alágbára líle

51:59

فَإِنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُواْ ذَنُوبًا مِّثۡلَ ذَنُوبِ أَصۡحَٰبِهِمۡ فَلَا يَسۡتَعۡجِلُونِ

Dájúdájú ìpín ìyà tí ó máa jẹ àwọn t’ó ṣàbòsí (wọ̀nyí) ni irú ìpín ìyà tí ó jẹ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ (irú) wọn. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe kán Mi lójú (nípa ìyà wọn)

51:60

فَوَيۡلٌ لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ مِن يَوۡمِهِمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ

Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ní ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.