Surah 56 · 96 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-Waqi'ah in Yoruba

In English with tafsir

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

56:1

إِذَا وَقَعَتِ ٱلۡوَاقِعَةُ

Nígbà tí Ìṣẹ̀lẹ̀ (Àjíǹde) bá ṣẹlẹ̀

56:2

لَيۡسَ لِوَقۡعَتِهَا كَاذِبَةٌ

kò sí irọ́ kan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀-E

56:3

خَافِضَةٌ رَّافِعَةٌ

ó máa mú (àwọn kan) wálẹ̀ (sínú Iná), ó sì máa gbé (àwọn kan) sókè (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra)

56:4

إِذَا رُجَّتِ ٱلۡأَرۡضُ رَجًّا

Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímìtìtì

56:5

وَبُسَّتِ ٱلۡجِبَالُ بَسًّا

àti nígbà tí Wọ́n bá fọ́ àwọn àpáta ní fífọ́ wómúwómú

56:6

فَكَانَتۡ هَبَآءً مُّنۢبَثًّا

wọ́n sì máa di eruku àfẹ́dànù - E

56:7

وَكُنتُمۡ أَزۡوَٰجًا ثَلَٰثَةً

ẹ̀yin sì máa jẹ́ oríṣi mẹ́ta

56:8

فَأَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ

ìjọ òsì àti ìjọ aṣíwájú. Àmọ́ nínú sūrah al-Balad; 90:18-19 àti sūrah az-Zalzalah; 99:6-8 Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pín wọn sí ìjọ méjì. Ìjọ méjì kúkú ni gbogbo ẹ̀dá ní ọ̀run 8 Àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún

56:9

وَأَصۡحَٰبُ ٱلۡمَشۡـَٔمَةِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَشۡـَٔمَةِ

Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì

56:10

وَٱلسَّٰبِقُونَ ٱلسَّٰبِقُونَ

Àwọn aṣíwájú sì ni àwọn aṣíwájú

56:11

أُوْلَٰٓئِكَ ٱلۡمُقَرَّبُونَ

Àwọn wọ̀nyẹn ni alásùn-únmọ́ (Allāhu)

56:12

فِي جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ

nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra

56:13

ثُلَّةٌ مِّنَ ٱلۡأَوَّلِينَ

Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́

56:14

وَقَلِيلٌ مِّنَ ٱلۡأٓخِرِينَ

Wọ́n sì kéré nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn

56:15

عَلَىٰ سُرُرٍ مَّوۡضُونَةٍ

(Wọn yóò wà) lórí ìtẹ́ tí wọ́n fi góòlù hun

56:16

مُّتَّكِـِٔينَ عَلَيۡهَا مُتَقَٰبِلِينَ

Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí rẹ̀, wọn sì máa dojú kọra wọn

56:17

يَطُوفُ عَلَيۡهِمۡ وِلۡدَٰنٌ مُّخَلَّدُونَ

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí darúgbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn

56:18

بِأَكۡوَابٍ وَأَبَارِيقَ وَكَأۡسٍ مِّن مَّعِينٍ

pẹ̀lú àwọn ife omi, ohun ìrọmi fẹ̀ǹfẹ̀ àti ife ọtí aládùn

56:19

لَّا يُصَدَّعُونَ عَنۡهَا وَلَا يُنزِفُونَ

Kò níí fọ́ wọn lórí; kò sì níí mú wọn húnrìrà

56:20

وَفَٰكِهَةٍ مِّمَّا يَتَخَيَّرُونَ

Èso tí wọn yóò máa ṣẹ̀ṣà nínú rẹ̀ (tún wà fún wọn)

56:21

وَلَحۡمِ طَيۡرٍ مِّمَّا يَشۡتَهُونَ

Àti ẹran ẹyẹ, èyí tí wọ́n ń fẹ́ (yó wà fún wọn)

56:22

وَحُورٌ عِينٌ

Àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ (tún wà fún wọn)

56:23

كَأَمۡثَٰلِ ٱللُّؤۡلُوِٕ ٱلۡمَكۡنُونِ

Wọ́n dà bí òkúta olówó-iyebíye tí wọ́n fi pamọ́

56:24

جَزَآءَۢ بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

(Ìwọ̀nyí ni) ẹ̀san fún ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

56:25

لَا يَسۡمَعُونَ فِيهَا لَغۡوًا وَلَا تَأۡثِيمًا

Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra

56:26

إِلَّا قِيلًا سَلَٰمًا سَلَٰمًا

Àyàfi ọ̀rọ̀ àlàáfíà, àlàáfíà

56:27

وَأَصۡحَٰبُ ٱلۡيَمِينِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلۡيَمِينِ

Àwọn èrò ọwọ́ ọtún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọtún

56:28

فِي سِدۡرٍ مَّخۡضُودٍ

(Wọn yóò wà) ní ìdí igi tí kò ní ẹ̀gún

56:29

وَطَلۡحٍ مَّنضُودٍ

àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ t’ó so jìgbìnnì

56:30

وَظِلٍّ مَّمۡدُودٍ

àti ibòji t’ó gbòòrò

56:31

وَمَآءٍ مَّسۡكُوبٍ

àti omi t’ó ń ṣàn láì dáwọ́ dúró

56:32

وَفَٰكِهَةٍ كَثِيرَةٍ

àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso

56:33

لَّا مَقۡطُوعَةٍ وَلَا مَمۡنُوعَةٍ

tí kò níí já (ní ọ̀dọ̀ wọn), kò sì níí dèèwọ̀ (fún wọn)

56:34

وَفُرُشٍ مَّرۡفُوعَةٍ

(Wọ́n máa wà lórí) ìtẹ́ tí wọ́n gbé sókè

56:35

إِنَّآ أَنشَأۡنَٰهُنَّ إِنشَآءً

Dájúdájú Àwa tún (àwọn obìnrin wọn) dá ní ẹ̀dá ọ̀tun

56:36

فَجَعَلۡنَٰهُنَّ أَبۡكَارًا

A sì ṣe wọ́n ní wúńdíá

56:37

عُرُبًا أَتۡرَابًا

olólùfẹ́ ọkọ. Wọ́n sì dọ́gba ní ọjọ́ orí

56:38

لِّأَصۡحَٰبِ ٱلۡيَمِينِ

(Wọ́n wà) fún àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún

56:39

ثُلَّةٌ مِّنَ ٱلۡأَوَّلِينَ

Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́

56:40

وَثُلَّةٌ مِّنَ ٱلۡأٓخِرِينَ

Wọ́n tún pọ̀ nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn

56:41

وَأَصۡحَٰبُ ٱلشِّمَالِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلشِّمَالِ

Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì

56:42

فِي سَمُومٍ وَحَمِيمٍ

(Wọn yóò wà) nínú atẹ́gùn gbígbóná àti omi gbígbóná

56:43

وَظِلٍّ مِّن يَحۡمُومٍ

àti ní abẹ́ ibòji eléèéfín dúdú

56:44

لَّا بَارِدٍ وَلَا كَرِيمٍ

kò tutù, kò sì dára

56:45

إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَبۡلَ ذَٰلِكَ مُتۡرَفِينَ

Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ onígbẹdẹmukẹ ṣíwájú ìyẹn

56:46

وَكَانُواْ يُصِرُّونَ عَلَى ٱلۡحِنثِ ٱلۡعَظِيمِ

Wọ́n sì máa ń ṣoríkunkun lórí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá

56:47

وَكَانُواْ يَقُولُونَ أَئِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ

Wọ́n sì máa ń wí pé: "Ṣé nígbà tí a bá di òkú, tí a sì di erùpẹ̀ àti egungun, ǹjẹ́ Wọn yóò tún gbé wa dìde ni

56:48

أَوَءَابَآؤُنَا ٱلۡأَوَّلُونَ

Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́

56:49

قُلۡ إِنَّ ٱلۡأَوَّلِينَ وَٱلۡأٓخِرِينَ

Sọ pé: "Dájúdájú àwọn ẹni àkọ́kọ́ àti àwọn ẹni Ìkẹ́yìn

56:50

لَمَجۡمُوعُونَ إِلَىٰ مِيقَٰتِ يَوۡمٍ مَّعۡلُومٍ

dájúdájú A óò kó wọn jọ papọ̀ ní àkókò ọjọ́ kan tí A ti mọ̀

56:51

ثُمَّ إِنَّكُمۡ أَيُّهَا ٱلضَّآلُّونَ ٱلۡمُكَذِّبُونَ

Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ̀yin olùṣìnà, olùpe-òdodo-nírọ́

56:52

لَأٓكِلُونَ مِن شَجَرٍ مِّن زَقُّومٍ

dájúdájú ẹ̀yin máa jẹ nínú igi zaƙƙūm (igi iwọ)

56:53

فَمَالِـُٔونَ مِنۡهَا ٱلۡبُطُونَ

Ikùn yín sì máa kún bámúbámú fún (jíjẹ) igi náà

56:54

فَشَٰرِبُونَ عَلَيۡهِ مِنَ ٱلۡحَمِيمِ

Ẹ̀yin yó sì máa mu omi gbígbóná lé e lórí

56:55

فَشَٰرِبُونَ شُرۡبَ ٱلۡهِيمِ

Ẹ̀yin yóò máa mu ún ní ìmumi ràkúnmí tí òǹgbẹ ń gbẹ

56:56

هَٰذَا نُزُلُهُمۡ يَوۡمَ ٱلدِّينِ

Èyí ni n̄ǹkan àlejò wọn ní Ọjọ́ ẹ̀san

56:57

نَحۡنُ خَلَقۡنَٰكُمۡ فَلَوۡلَا تُصَدِّقُونَ

Àwa l’A ṣẹ̀dá yín. Kí ni kò jẹ́ kí ẹ gbàgbọ́ lódodo

56:58

أَفَرَءَيۡتُم مَّا تُمۡنُونَ

Ẹ sọ fún Mi nípa àtọ̀ tí ẹ̀ ń dà jáde (sínú àpòlùkẹ́)

56:59

ءَأَنتُمۡ تَخۡلُقُونَهُۥٓ أَمۡ نَحۡنُ ٱلۡخَٰلِقُونَ

ṣé ẹ̀yin lẹ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni tàbí Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀

56:60

نَحۡنُ قَدَّرۡنَا بَيۡنَكُمُ ٱلۡمَوۡتَ وَمَا نَحۡنُ بِمَسۡبُوقِينَ

Àwa l’A yan kádàrá (ọjọ́) ikú fún gbogbo yín. Àwa kò sì lè kágara

56:61

عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ أَمۡثَٰلَكُمۡ وَنُنشِئَكُمۡ فِي مَا لَا تَعۡلَمُونَ

láti fi irú yín pààrọ̀ yín, kí á sì tun yín dá sínú ohun tí ẹ kò mọ̀

56:62

وَلَقَدۡ عَلِمۡتُمُ ٱلنَّشۡأَةَ ٱلۡأُولَىٰ فَلَوۡلَا تَذَكَّرُونَ

Ẹ kúkú mọ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́, ẹ ò ṣe lo ìrántí

56:63

أَفَرَءَيۡتُم مَّا تَحۡرُثُونَ

Ẹ sọ fún Mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gbìn sínú ilẹ̀

56:64

ءَأَنتُمۡ تَزۡرَعُونَهُۥٓ أَمۡ نَحۡنُ ٱلزَّٰرِعُونَ

ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń jẹ́ kí ó hù jáde ni tàbí Àwa l’À ń jẹ́ kí ó hù jáde

56:65

لَوۡ نَشَآءُ لَجَعَلۡنَٰهُ حُطَٰمًا فَظَلۡتُمۡ تَفَكَّهُونَ

Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá sọ ọ́ di gbígbẹ, ẹ̀yin yó sì máa ṣèèmọ̀ (tí ẹ óò máa ká àbámọ̀)

56:66

إِنَّا لَمُغۡرَمُونَ

(Ẹ̀yin yó sì wí pé:) "Dájúdájú àwa ti di onígbèsè

56:67

بَلۡ نَحۡنُ مَحۡرُومُونَ

(Àwọn mìíràn yó sì wí pé:) "Rárá o! Wọ́n ṣe ìkórè oko ní èèwọ̀ fún wa ni

56:68

أَفَرَءَيۡتُمُ ٱلۡمَآءَ ٱلَّذِي تَشۡرَبُونَ

Ẹ sọ fún mi nípa omi tí ẹ̀ ń mu

56:69

ءَأَنتُمۡ أَنزَلۡتُمُوهُ مِنَ ٱلۡمُزۡنِ أَمۡ نَحۡنُ ٱلۡمُنزِلُونَ

ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti inú ẹ̀ṣújò ni tàbí Àwa l’À ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀

56:70

لَوۡ نَشَآءُ جَعَلۡنَٰهُ أُجَاجًا فَلَوۡلَا تَشۡكُرُونَ

Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá ṣe é ní omi t’ó móró. Ẹ ò ṣe máa dúpẹ́

56:71

أَفَرَءَيۡتُمُ ٱلنَّارَ ٱلَّتِي تُورُونَ

Ẹ sọ fún Mi nípa iná tí ẹ̀ ń dá

56:72

ءَأَنتُمۡ أَنشَأۡتُمۡ شَجَرَتَهَآ أَمۡ نَحۡنُ ٱلۡمُنشِـُٔونَ

ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣẹ̀dá igi rẹ̀ ni tàbí Àwa ni Aṣẹ̀dá

56:73

نَحۡنُ جَعَلۡنَٰهَا تَذۡكِرَةً وَمَتَٰعًا لِّلۡمُقۡوِينَ

Àwa ṣe iná ayé ní ìrántí (fún Iná ọ̀run) àti n̄ǹkan èlò fún àwọn onírìn-àjò

56:74

فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ

Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi

56:75

فَلَآ أُقۡسِمُ بِمَوَٰقِعِ ٱلنُّجُومِ

Mò ń búra pẹ̀lú àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀

56:76

وَإِنَّهُۥ لَقَسَمٌ لَّوۡ تَعۡلَمُونَ عَظِيمٌ

Dájúdájú ìbúra ńlá ni, tí ẹ bá mọ̀

56:77

إِنَّهُۥ لَقُرۡءَانٌ كَرِيمٌ

Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni n̄ǹkan kíké alápọ̀n-ọ́nlé

56:78

فِي كِتَٰبٍ مَّكۡنُونٍ

(t’ó wà) nínú Tírà ààbò (nínú Laohul-Mahfūṭḥ)

56:79

لَّا يَمَسُّهُۥٓ إِلَّا ٱلۡمُطَهَّرُونَ

Kò sí ẹni tó lè fọwọ́ kàn án (ní ọ̀dọ̀ Allāhu) àfi àwọn ẹni mímọ́ (ìyẹn, àwọn mọlāika)

56:80

تَنزِيلٌ مِّن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Wọ́n sọ̀ al-Ƙur’ān kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

56:81

أَفَبِهَٰذَا ٱلۡحَدِيثِ أَنتُم مُّدۡهِنُونَ

Nítorí náà, ṣé ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí l’ẹ̀ ń pè nírọ́

56:82

وَتَجۡعَلُونَ رِزۡقَكُمۡ أَنَّكُمۡ تُكَذِّبُونَ

Ẹ sì ń sọ ìdúpẹ́ arísìkí yín di pé dájúdájú ẹ̀ ń pe òdodo nírọ́

56:83

فَلَوۡلَآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلۡحُلۡقُومَ

Kí ni ó máa ti rí (fun yín) nígbà tí ẹ̀mí (yín) bá dé ọ̀nà ọ̀fun

56:84

وَأَنتُمۡ حِينَئِذٍ تَنظُرُونَ

tí ẹ̀yin yó sì máa wòran nígbà yẹn

56:85

وَنَحۡنُ أَقۡرَبُ إِلَيۡهِ مِنكُمۡ وَلَٰكِن لَّا تُبۡصِرُونَ

Àwa sì súnmọ́ ọn ju ẹ̀yin lọ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ríran

56:86

فَلَوۡلَآ إِن كُنتُمۡ غَيۡرَ مَدِينِينَ

Ẹ̀yin kò ṣe jẹ́ ẹni tí A ò níí gbẹ̀san lára rẹ̀

56:87

تَرۡجِعُونَهَآ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ

kí ẹ sì dá (ẹ̀mí tí ó fẹ́ bọ́) padà, tí ẹ bá jẹ́ olódodo

56:88

فَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلۡمُقَرَّبِينَ

Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (Wa)

56:89

فَرَوۡحٌ وَرَيۡحَانٌ وَجَنَّتُ نَعِيمٍ

ìsinmi, èsè t’ó dára àti Ọgbà Ìdẹ̀ra (ni tirẹ̀)

56:90

وَأَمَّآ إِن كَانَ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلۡيَمِينِ

Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún

56:91

فَسَلَٰمٌ لَّكَ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلۡيَمِينِ

àlàáfíà ni fún ọ láààrin àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún

56:92

وَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلۡمُكَذِّبِينَ ٱلضَّآلِّينَ

Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn olùṣìnà

56:93

فَنُزُلٌ مِّنۡ حَمِيمٍ

n̄ǹkan àlejò (wọn) ni omi gbígbóná

56:94

وَتَصۡلِيَةُ جَحِيمٍ

àti wíwọ inú iná Jẹhīm

56:95

إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ حَقُّ ٱلۡيَقِينِ

Dájúdájú èyí, òhun ni òdodo t’ó dájú

56:96

فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ

Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.